Amo 2:1-3
Amo 2:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
BAYI li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Moabu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o ti sun egungun ọba Edomu di ẽrú. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara Moabu, yio si jó ãfin Kirioti wọnni run: Moabu yio si kú pẹlu ariwo, pẹlu iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè: Emi o si ké onidajọ kurò lãrin rẹ̀, emi o si pa gbogbo ọmọ-alade inu rẹ̀ pẹlu rẹ̀; li Oluwa wi.
Amo 2:1-3 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní: “Àwọn ará Moabu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n sọná sí egungun ọba Edomu, wọ́n sun ún, ó jóná ráúráú. Nítorí náà, n óo sọ iná sí Moabu, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Kerioti ní àjórun. Ninu ariwo ogun ati ti fèrè ni Moabu yóo parun sí, n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ run.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Amo 2:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, Nítorí ó ti sun ún, di eérú, egungun ọba Edomu Èmi yóò rán iná sí orí Moabu èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run. Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,” ni OLúWA wí.