Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Iṣe Apo 9:36YBCV(Bibeli Mimọ)

Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Joppa ti a npè ni Tabita, ni itumọ̀ rẹ̀ ti a npè ni Dorka: obinrin yi pọ̀ ni iṣẹ ore, ati itọrẹ-ãnu ti o ṣe.

Iṣe Apo 9:36BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita (èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi); obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe.

Iṣe Apo 9:36YCE(Yoruba Bible)

Ọmọ-ẹ̀yìn kan wà ní Jọpa, tí ó jẹ́ obinrin, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tabita, tabi Dọkasi ní èdè Giriki. (Ìtumọ̀ rẹ̀ ni èkùlù.) Obinrin yìí jẹ́ ẹnìkan tíí máa ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, ó sì láàánú pupọ.