Iṣe Apo 9:21-31
Iṣe Apo 9:21-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o ngbọ́, nwọn si wipe, Ẹniti o ti fõro awọn ti npè orukọ yi ni Jerusalemu kọ li eyi, ti o si ti itori na wá si ihinyi, lati mu wọn ni didè lọ sọdọ awọn olori alufa? Ṣugbọn Saulu npọ̀ si i li agbara o si ndãmu awọn Ju ti o ngbe Damasku, o nfi hàn pe, eyi ni Kristi na. Lẹhin igbati ọjọ pipọ kọja, awọn Ju ngbìmọ lati pa a: Ṣugbọn ìditẹ̀ wọn di mimọ̀ fun Saulu. Nwọn si nṣọ ẹnu-bode pẹlu li ọsán ati li oru lati pa a. Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mu u li oru, nwọn si sọ̀ ọ kalẹ lara odi ninu agbọ̀n. Nigbati Saulu si de Jerusalemu, o pete ati da ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn ọmọ-ẹhin: gbogbo nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, nitori nwọn kò gbagbọ́ pe ọmọ-ẹhin kan ni. Ṣugbọn Barnaba mu u, o si sìn i lọ sọdọ awọn aposteli, o si sọ fun awọn bi o ti ri Oluwa li ọ̀na, ati pe o ti ba a sọ̀rọ, ati bi o ti fi igboiya wasu ni Damasku li orukọ Jesu. O si wà pẹlu wọn, o nwọle o si njade ni Jerusalemu. O si nfi igboiya sọ̀rọ li orukọ Jesu Oluwa, o nsọrọ lòdi si awọn ara Hellene, o si njà wọn niyàn: ṣugbọn nwọn npete ati pa a. Nigbati awọn arakunrin si mọ̀, nwọn mu u sọkalẹ lọ si Kesarea, nwọn si rán a lọ si Tarsu. Nigbana ni ijọ wà li alafia yi gbogbo Judea ká ati ni Galili ati ni Samaria, nwọn nfẹsẹmulẹ; nwọn nrìn ni ìbẹru Oluwa, ati ni itunu Ẹmí Mimọ́, nwọn npọ̀ si i.
Iṣe Apo 9:21-31 Yoruba Bible (YCE)
Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n ní “Ará ibí yìí kọ́ ni ó ń pa àwọn tí ó ń pe orúkọ yìí ní Jerusalẹmu, tí ó tún wá síhìn-ín láti fi ẹ̀wọ̀n dè wọ́n, tí ó fẹ́ fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa?” Ṣugbọn ńṣe ni Saulu túbọ̀ ń lágbára sí i. Àwọn Juu tí ó ń gbé Damasku kò mọ ohun tí wọ́n le wí mọ́, nítorí ó fi ẹ̀rí hàn pé Jesu ni Mesaya. Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á. Ṣugbọn Saulu gbọ́ nípa ète wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu odi ìlú tọ̀sán-tòru kí wọ́n baà lè pa á. Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e sinu apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí odi ìlú. Nígbà tí Saulu dé Jerusalẹmu, ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn ẹ̀rù rẹ̀ ń bà wọ́n; wọn kò gbàgbọ́ pé ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku. Ó bá ń bá wọn gbé ní Jerusalẹmu, ó ń wọlé, ó ń jáde, ó ń fi ìgboyà waasu lórúkọ Oluwa, ó ń bá àwọn Juu tí ó ń sọ èdè Giriki jiyàn. Ṣugbọn wọ́n gbèrò láti pa á. Nígbà tí àwọn onigbagbọ mọ̀, wọ́n sìn ín lọ sí Kesaria, wọ́n fi ranṣẹ sí Tasu. Gbogbo ìjọ ní Judia, ati Galili, ati Samaria wà ní alaafia, wọ́n sì fìdí múlẹ̀. Wọ́n ń gbé ìgbé-ayé wọn pẹlu ìbẹ̀rù Oluwa, wọ́n sì ń pọ̀ sí i nípa ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.
Iṣe Apo 9:21-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fóòro àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerusalẹmu? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhín yìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.” Ṣùgbọ́n Saulu ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Damasku, ó fihàn pé, èyí ni Kristi náà. Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n. Nígbà ti Saulu sì de Jerusalẹmu ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni. Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu. Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa. Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a. Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesarea, wọ́n sì rán an lọ sí Tarsu. Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i.