Iṣe Apo 8:1-5
Iṣe Apo 8:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
SAULU si li ohùn si ikú rẹ̀. Li akoko na, inunibini nla kan dide si ijọ ti o wà ni Jerusalemu; a si tú gbogbo wọn kalẹ já àgbegbe Judea on Samaria, afi awọn aposteli. Awọn enia olufọkànsin si dì okú Stefanu, nwọn si pohùnrére ẹkún kikan sori rẹ̀. Ṣugbọn Saulu, o ndà ijọ enia Ọlọrun ru, o nwọ̀ ojõjũle, o si nmu awọn ọkunrin ati obinrin, o si nfi wọn sinu tubu. Awọn ti nwọn si túka lọ si ibi gbogbo, nwọn nwasu ọ̀rọ na. Filippi si sọkalẹ lọ si ilu Samaria, o nwasu Kristi fun wọn.
Iṣe Apo 8:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Saulu bá wọn lọ́wọ́ sí ikú rẹ̀. Láti ọjọ́ náà ni inúnibíni ńlá ti bẹ̀rẹ̀ sí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn onigbagbọ bá túká lọ sí gbogbo agbègbè Judia ati Samaria. Àwọn aposteli nìkan ni kò kúrò ní ìlú. Àwọn olùfọkànsìn sin òkú Stefanu, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ pupọ lórí rẹ̀. Ṣugbọn Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ rú. Ó ń wọ ojúlé kiri, ó ń fa tọkunrin tobinrin jáde, lọ sẹ́wọ̀n. Àwọn tí wọ́n túká bá ń lọ káàkiri, wọ́n ń waasu ọ̀rọ̀ náà. Filipi lọ sí ìlú Samaria kan, ó waasu fún wọn nípa Kristi.
Iṣe Apo 8:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀. Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli. Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Stefanu lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀. Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú. Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà. Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn.