Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Iṣe Apo 8:1YBCV(Bibeli Mimọ)

SAULU si li ohùn si ikú rẹ̀. Li akoko na, inunibini nla kan dide si ijọ ti o wà ni Jerusalemu; a si tú gbogbo wọn kalẹ já àgbegbe Judea on Samaria, afi awọn aposteli.

Iṣe Apo 8:1BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀. Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli.

Iṣe Apo 8:1YCE(Yoruba Bible)

Saulu bá wọn lọ́wọ́ sí ikú rẹ̀. Láti ọjọ́ náà ni inúnibíni ńlá ti bẹ̀rẹ̀ sí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn onigbagbọ bá túká lọ sí gbogbo agbègbè Judia ati Samaria. Àwọn aposteli nìkan ni kò kúrò ní ìlú.