Iṣe Apo 7:11-22
Iṣe Apo 7:11-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iyan kan si wá imu ni gbogbo ilẹ Egipti ati ni Kenaani, ati ipọnju pipọ: awọn baba wa kò si ri onjẹ. Ṣugbọn nigbati Jakọbu gbọ́ pe alikama mbẹ ni Egipti, o rán awọn baba wa lọ lẹrinkini. Ati nigba keji Josefu fi ara rẹ̀ hàn fun awọn arakunrin rẹ̀; a si fi awọn ará Josefu hàn fun Farao. Josefu si ranṣẹ, o si pè Jakọbu baba rẹ̀, ati gbogbo awọn ibatan rẹ̀ sọdọ rẹ̀, arundilọgọrin ọkàn. Jakọbu si sọkalẹ lọ si Egipti, o si kú, on ati awọn baba wa, A si gbe wọn lọ si Sikemu, a si tẹ́ wọn sinu ibojì ti Abrahamu rà ni iye-owo fadaka lọwọ awọn ọmọ Emoru baba Sikemu. Ṣugbọn bi akokò ileri ti Oluwa ṣe fun Abrahamu ti kù si dẹ̀dẹ, awọn enia na nrú, nwọn si nrẹ̀ ni Egipti, Titi ọba miran fi jẹ lori Egipti ti kò mọ̀ Josefu. On na li o ṣe àrekerekè si awọn ibatan wa, nwọn si hùwa buburu si awọn baba wa, tobẹ̃ ti nwọn fi já awọn ọmọ-ọwọ wọn kuro lọwọ wọn nitori ki nwọn ki o máṣe yè. Li akokò na li a bí Mose, ẹniti o li ẹwà pipọ, ti nwọn si bọ́ li oṣù mẹta ni ile baba rẹ̀: Nigbati nwọn si gbe e sọnù, ọmọbinrin Farao he e, o si tọ́ ọ dàgba li ọmọ ara rẹ̀. A si kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ará Egipti, o si pọ̀ li ọ̀rọ ati ni iṣe.
Iṣe Apo 7:11-22 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, ìyàn mú ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ní ilẹ̀ Kenaani. Eléyìí mú ìṣòro pupọ wá. Àwọn eniyan wa kò bá rí oúnjẹ jẹ. Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé oúnjẹ wà ní Ijipti, ó kọ́kọ́ rán àwọn baba wa lọ. Ní ẹẹkeji ni àwọn arakunrin rẹ̀ tó mọ ẹni tí Josẹfu jẹ́. A sì fi ìdílé Josẹfu han Farao. Josẹfu bá ranṣẹ láti pe Jakọbu baba rẹ̀ wá ati gbogbo àwọn ẹbí rẹ̀. Wọ́n jẹ́ eniyan marunlelaadọrin (75). Jakọbu bá lọ sí Ijipti. Níbẹ̀ ni ó kú sí, òun ati àwọn baba wa náà. Wọ́n gbé òkú wọn lọ sí Ṣekemu, wọ́n sin wọ́n sinu ibojì tí Abrahamu fowó rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori ní Ṣekemu. “Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún Abrahamu yóo ṣẹ, àwọn eniyan náà wá túbọ̀ ń pọ̀ níye ní Ijipti. Nígbà tó yá, ọba mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ijipti. Ọba yìí bá fi ọgbọ́n àrékérekè bá orílẹ̀-èdè wa lò. Ó dá àwọn baba wa lóró, ó mú kí wọ́n máa sọ ọmọ nù, kí wọ́n baà lè kú. Ní àkókò yìí ni a bí Mose. Ó dára lọ́mọ pupọ. Àwọn òbí rẹ̀ tọ́ ọ fún oṣù mẹta ninu ilé baba rẹ̀ Nígbà tí wọ́n sọ ọ́ nù, ni ọmọ Farao, obinrin, bá tọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ti ara rẹ̀. Gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Ijipti ni wọ́n fi kọ́ Mose. Ati ọ̀rọ̀ sísọ, ati iṣẹ́ ṣíṣe kò sí èyí tí kò mọ̀ ọ́n ṣe.
Iṣe Apo 7:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti àti ni Kenaani, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé alikama ń bẹ ni Ejibiti, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní. Nígbà kejì Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Farao. Lẹ́yìn èyí, Josẹfu ránṣẹ́ pe Jakọbu baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrùndínlọ́gọ́rin ọkàn. Nígbà náà ni Jakọbu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí. A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣekemu, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Abrahamu rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Amori ní Ṣekemu ní iye owó wúrà kan. “Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Abrahamu ṣẹ kù sí dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbèrú si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Ejibiti. Ṣùgbọ́n ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. Òun náà ni ó ṣe àrékérekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè. “Ní àkókò náà ni a bí Mose, (ẹni tí ó dára ní ojú Ọlọ́run) ẹni tí ó lẹ́wà púpọ̀, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀. Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Farao gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀. A sì kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ara Ejibiti, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.