Iṣe Apo 6:5-6
Iṣe Apo 6:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀rọ na si tọ́ loju gbogbo ijọ: nwọn si yàn Stefanu, ọkunrin ti o kún fun igbagbọ́ ati fun Ẹmí Mimọ́, ati Filippi ati Prokoru, ati Nikanoru, ati Timoni, ati Parmena, ati Nikola alawọṣe Ju ara Antioku: Ẹniti nwọn mu duro niwaju awọn aposteli: nigbati nwọn si gbadura, nwọn fi ọwọ́ le wọn.
Iṣe Apo 6:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀rọ̀ yìí dára lójú gbogbo àwùjọ, wọ́n bá yan Stefanu. Stefanu yìí jẹ́ onigbagbọ tọkàntọkàn, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n yan Filipi náà ati Prokoru ati Nikanọ ati Timoni ati Pamena ati Nikolausi ará Antioku tí ó ti gba ẹ̀sìn àwọn Juu. Wọ́n kó wọn wá siwaju àwọn aposteli; wọ́n gbadura, wọ́n bá gbé ọwọ́ lé wọn lórí.
Iṣe Apo 6:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Stefanu, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti Filipi, àti Prokoru, àti Nikanoru, àti Timoni, àti Parimena, àti Nikolasi aláwọ̀ṣe Júù ará Antioku. Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Aposteli; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.