Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 6:5YBCV(Bibeli Mimọ)
Ọ̀rọ na si tọ́ loju gbogbo ijọ: nwọn si yàn Stefanu, ọkunrin ti o kún fun igbagbọ́ ati fun Ẹmí Mimọ́, ati Filippi ati Prokoru, ati Nikanoru, ati Timoni, ati Parmena, ati Nikola alawọṣe Ju ara Antioku
Iṣe Apo 6:5BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Stefanu, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti Filipi, àti Prokoru, àti Nikanoru, àti Timoni, àti Parimena, àti Nikolasi aláwọ̀ṣe Júù ará Antioku.
Iṣe Apo 6:5YCE(Yoruba Bible)
Ọ̀rọ̀ yìí dára lójú gbogbo àwùjọ, wọ́n bá yan Stefanu. Stefanu yìí jẹ́ onigbagbọ tọkàntọkàn, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n yan Filipi náà ati Prokoru ati Nikanọ ati Timoni ati Pamena ati Nikolausi ará Antioku tí ó ti gba ẹ̀sìn àwọn Juu.
Pín
Iṣe Apo 6YCE