Iṣe Apo 6:2-4
Iṣe Apo 6:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn mejila si pè ọpọlọpọ awọn ọmọ-ẹhin jọ̀ sọdọ, nwọn wipe, Kò yẹ ti awa iba fi ọ̀rọ Ọlọrun silẹ, ki a si mã ṣe iranṣẹ tabili. Nitorina, ará, ẹ wo ọkunrin meje ninu nyin, olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmí Mimọ́ ati fun ọgbọ́n, ẹniti awa iba yàn si iṣẹ yi. Ṣugbọn awa o duro ṣinṣin ninu adura igbà, ati ninu iṣẹ iranṣẹ ọ̀rọ na.
Iṣe Apo 6:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn aposteli mejila bá pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yòókù jọ, wọ́n ní, “Kò yẹ kí á fi iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílẹ̀, kí á máa ṣe ètò oúnjẹ. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ wá ẹni meje láàrin yín, tí wọ́n ní orúkọ rere, tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ ati ọgbọ́n, kí á yàn wọ́n láti mójútó ètò yìí. Àwa ní tiwa, a óo tẹra mọ́ adura gbígbà ati iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ ìyìn rere.”
Iṣe Apo 6:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì. Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí. Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”