Skip to content
Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Iṣe Apo 28:25YBCV(Bibeli Mimọ)

Nigbati ohùn wọn kò ṣọ̀kan lãrin ara wọn, nwọn tuká, lẹhin igbati Paulu sọ̀rọ kan pe, Otitọ li Ẹmí Mimọ́ sọ lati ẹnu woli Isaiah wá fun awọn baba wa

Iṣe Apo 28:25BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrín ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Paulu sọ̀rọ̀ kan pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah wí pé

Iṣe Apo 28:25YCE(Yoruba Bible)

Nígbà tí ohùn wọn kò dọ́gba láàrin ara wọn, wọ́n bá ń túká lọ. Paulu wá tún sọ gbolohun kan, ó ní, “Òtítọ́ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sọ láti ẹnu wolii Aisaya sí àwọn baba-ńlá yín.