Iṣe Apo 26:17-18
Iṣe Apo 26:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o ma gbà ọ lọwọ awọn enia, ati lọwọ awọn Keferi, ti emi rán ọ si nisisiyi, Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.
Iṣe Apo 26:17-18 Yoruba Bible (YCE)
N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí n óo rán ọ sí. Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’
Iṣe Apo 26:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Èmi rán ọ sí wọn nísinsin yìí láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’