Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 25:9YBCV(Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Festu nfẹ gbà oju're lọdọ awọn Ju, o si da Paulu lohùn, wipe, Iwọ ha nfẹ goke lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀ niwaju mi bi?
Iṣe Apo 25:9BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Festu ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Paulu lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?”
Iṣe Apo 25:9YCE(Yoruba Bible)
Nítorí pé Fẹstu ń wá ojurere àwọn Juu, ó bi Paulu pé, “Ṣé o óo kálọ sí Jerusalẹmu, kí n dá ẹjọ́ yìí níbẹ̀?”