Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 25:26YBCV(Bibeli Mimọ)
Nipasẹ ẹniti emi kò ri ohun kan dajudaju lati kọwe si oluwa mi. Nitorina ni mo ṣe mu u jade wá siwaju nyin, ati pe siwaju rẹ, Agrippa ọba, pãpã lẹhin ti a ba ti wadi rẹ̀, ki emi ki o le ri ohun ti emi ó kọ.
Iṣe Apo 25:26BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èmi kò ri ohun kan dájúdájú láti kọ̀wé sí olúwa mi. Nítorí náà ni mo ṣe mú un jáde wá síwájú yín, àní síwájú rẹ ọba Agrippa, kí o fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí a ba tí ṣe ìwádìí rẹ̀, èmi yóò lè rí ohun tí èmi yóò kọ.
Iṣe Apo 25:26YCE(Yoruba Bible)
Ṣugbọn n kò ní ohun kan pàtó láti kọ sí oluwa mi nípa rẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi mú un wá siwaju yín, pàápàá siwaju Agiripa aláyélúwà, kí n lè rí ohun tí n óo kọ nípa rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti yẹ ọ̀rọ̀ náà wò.