Iṣe Apo 25:1-22 - Compare All Versions

Iṣe Apo 25:1-22 YBCV (Bibeli Mimọ)

NJẸ nigbati Festu de ilẹ na, lẹhin ijọ mẹta o gòke lati Kesarea lọ si Jerusalemu. Awọn olori alufa ati awọn enia pataki ninu awọn Ju fi Paulu sùn u, nwọn si bẹ̀ ẹ, Nwọn nwá oju're rẹ̀ si Paulu, ki o le ranṣẹ si i wá si Jerusalemu: nwọn ndèna dè e lati pa a li ọna. Ṣugbọn Festu dahun pe, a pa Paulu mọ́ ni Kesarea, ati pe on tikara on nmura ati pada lọ ni lọ̃lọ̃yi. O ni, njẹ awọn ti o ba to ninu nyin, ki nwọn ba mi sọkalẹ lọ, bi ìwa buburu kan ba wà lọwọ ọkunrin yi, ki nwọn ki o fi i sùn. Kò si gbe ãrin wọn ju ijọ mẹjọ tabi mẹwa lọ, o sọkalẹ lọ si Kesarea; ni ijọ keji o joko lori itẹ́ idajọ, o si paṣẹ pè ki a mu Paulu wá. Nigbati o si de, awọn Ju ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá duro yi i ká, nwọn nkà ọ̀ran pipọ ti o si buru si Paulu lọrùn, ti nwọn kò le ladi. Paulu si wi ti ẹnu rẹ̀ pe, Emi kò ṣẹ ẹṣẹkẹṣẹ kan si ofin awọn Ju, tabi si tẹmpili, tabi si Kesari. Ṣugbọn Festu nfẹ gbà oju're lọdọ awọn Ju, o si da Paulu lohùn, wipe, Iwọ ha nfẹ goke lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀ niwaju mi bi? Paulu si wipe, Niwaju itẹ́ idajọ Kesari ni mo duro nibiti o yẹ ki a ṣe ẹjọ mi: emi kò ṣẹ awọn Ju, bi iwọ pẹlu ti mọ̀ daju. Njẹ bi mo ba ṣẹ̀, ti mo si ṣe ohun kan ti o yẹ fùn ikú, emi kò kọ̀ lati kú: ṣugbọn bi kò ba si nkan wọnni ninu ohun ti awọn wọnyi fi mi sùn si, ẹnikan kò le fi mi ṣe oju're fun wọn. Mo fi ọ̀ran mi lọ Kesari. Nigbana ni Festu lẹhin ti o ti ba ajọ igbìmọ sọ̀rọ, o dahùn pe, Iwọ ti fi ọ̀ran rẹ lọ Kesari: lọdọ Kesari ni iwọ ó lọ. Lẹhin ijọ melokan, Agrippa ọba, ati Bernike sọkalẹ wá si Kesarea lati kí Festu. Bi nwọn si ti wà nibẹ̀ li ọjọ pipọ, Festu mu ọ̀ran Paulu wá siwaju ọba, wipe, Feliksi fi ọkunrin kan silẹ li ondè: Ẹniti awọn olori alufa ati awọn agbàgba awọn Ju fi sùn nigbati mo wà ni Jerusalemu nwọn nfẹ ki n da a lẹbi. Awọn ẹniti mo si da lohùn pe, Kì iṣe iṣe awọn ara Romu lati da ẹnikẹni lẹbi, ki ẹniti a fisùn ki o to kò awọn olufisùn rẹ̀ loju, ki o si ri àye wi ti ẹnu rẹ̀, nitori ọ̀ran ti a kà si i lọrùn, Nitorina nigbati nwọn jùmọ wá si ihinyi, emi kò jafara, nijọ keji mo joko lori itẹ́ idajọ, mo si paṣẹ pe ki a mu ọkunrin na wá. Nigbati awọn olufisùn na dide, nwọn kò kà ọ̀ran buburu iru eyi ti mo rò si i lọrùn. Ṣugbọn nwọn ni ọ̀ran kan si i, niti isin wọn, ati niti Jesu kan ti o ti kú, ti Paulu tẹnumọ́ pe o wà lãye. Bi emi kò si ti mọ̀ bi a iti wadi nkan wọnyi, mo bi i lere bi o nfẹ lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀. Ṣugbọn nigbati Paulu fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, pe ki a pa on mọ fun idajọ rẹ̀, mo paṣẹ pe ki a pa a mọ titi emi o fi le rán a lọ sọdọ Kesari. Agrippa si wi fun Festu pe, Emi pẹlu fẹ lati gbọ́ ọrọ ọkunrin na tikarami. O si wipe, Lọla iwọ o gbọ ọ.

Iṣe Apo 25:1-22 YCE (Yoruba Bible)

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta tí Fẹstu dé sí agbègbè ibi iṣẹ́ rẹ̀, ó lọ sí Jerusalẹmu láti Kesaria. Àwọn olórí alufaa ati àwọn aṣiwaju àwọn Juu bá gbé ọ̀rọ̀ Paulu siwaju rẹ̀. Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣe oore kan fún wọn, kí ó fi Paulu ranṣẹ sí Jerusalẹmu. Èrò wọn ni láti dènà dè é, kí wọ́n baà lè pa á. Ṣugbọn Fẹstu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ń ṣọ́ Paulu ní Kesaria; èmi náà kò sì ní pẹ́ pada sibẹ. Ẹ jẹ́ kí àwọn aṣiwaju yín bá mi kálọ kí wọ́n wá sọ bí wọ́n bá ní ẹ̀sùn kan sí i.” Kò lò ju bí ọjọ́ mẹjọ tabi mẹ́wàá lọ pẹlu wọn, ni ó bá pada lọ sí Kesaria. Ní ọjọ́ keji ó jókòó ninu kóòtù, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wá. Nígbà tí Paulu dé, àwọn Juu tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu tò yí i ká, wọ́n ń ro ẹjọ́ ńláńlá mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ lọ́tùn-ún lósì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ninu gbogbo ẹjọ́ tí wọ́n rò. Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ti ẹnu rẹ̀, ó ní, “N kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí òfin àwọn Juu tabi sí Tẹmpili; n kò sì ṣẹ Kesari.” Nítorí pé Fẹstu ń wá ojurere àwọn Juu, ó bi Paulu pé, “Ṣé o óo kálọ sí Jerusalẹmu, kí n dá ẹjọ́ yìí níbẹ̀?” Paulu dáhùn ó ní, “Níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ ọba Kesari ni mo gbé dúró, níbẹ̀ ni a níláti dá ẹjọ́ mi. N kò ṣẹ àwọn Juu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀ dájúdájú. Bí mo bá rú òfin, tabi bí mo bá ṣe ohun tí ó yẹ kí á dá mi lẹ́bi ikú, n kò bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ má pa mí. Ṣugbọn bí kò bá sí ohun kan tí a lè rí dìmú ninu ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí, ẹnikẹ́ni kò lè fi mí wá ojurere wọn. Ẹ gbé ẹjọ́ mi lọ siwaju Kesari ọba.” Fẹstu forí-korí pẹlu àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀, ó wá dáhùn pé, “O ti gbé ẹjọ́ rẹ lọ siwaju ọba Kesari; nítorí náà o gbọdọ̀ lọ sọ́dọ̀ ọba Kesari.” Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Agiripa ọba ati Berenike wá kí Fẹstu ní Kesaria. Wọ́n pẹ́ díẹ̀ níbẹ̀. Fẹstu wá fi ọ̀rọ̀ Paulu siwaju ọba. Ó ní, “Ọkunrin kan wà níhìn-ín tí Fẹliksi fi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Nígbà tí mo lọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà àwọn Juu rojọ́ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ mí pé kí n dá a lẹ́bi. Mo dá wọn lóhùn pé kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti fa ẹnikẹ́ni lé àwọn olùfisùn rẹ̀ lọ́wọ́ láì fún un ní anfaani láti fojúkojú pẹlu wọn, kí ó sì sọ ti ẹnu rẹ̀ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Nígbà tí wọ́n bá mi wá síhìn-ín, n kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ní ọjọ́ keji mo jókòó ní kóòtù, mo pàṣẹ kí wọ́n mú ọkunrin náà wá. Nígbà tí àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án dìde láti sọ̀rọ̀, wọn kò mẹ́nuba irú àwọn ọ̀ràn tí mo rò pé wọn yóo sọ. Àríyànjiyàn nípa ẹ̀sìn oriṣa wọn, ati nípa ẹnìkan tí ń jẹ́ Jesu ni ohun tí wọn ń jà sí. Jesu yìí ti kú, ṣugbọn Paulu ní ó wà láàyè. Ọ̀rọ̀ náà rú mi lójú; mo bá bi ọkunrin náà bí ó bá fẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, kí á ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà níbẹ̀. Ṣugbọn Paulu ní kí á fi òun sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí Kesari yóo fi lè gbọ́ ẹjọ́ òun. Mo bá pàṣẹ kí wọ́n fi í sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí tí n óo fi lè fi ranṣẹ sí Kesari.” Agiripa bá wí fún Fẹstu pé, “Èmi fúnra mi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkunrin náà.” Fẹstu dáhùn ó ní, “Ẹ óo gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ lọ́la.”

Iṣe Apo 25:1-22 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí ó dé sí ilẹ̀ náà, Festu gòkè láti Kesarea lọ sì Jerusalẹmu, ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Paulu wá, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́. Wọ́n tọrọ lọ́wọ́ Festu, kí ó bá le ṣe ojúrere fún wọn, kí ó bá à lè jẹ́ kí wọn mú Paulu wá sí Jerusalẹmu, wọn ń gbìmọ̀ láti dènà dè é, kí wọn sì pa á ní ọ̀nà. Ṣùgbọ́n Festu dáhùn pé, “A pa Paulu mọ́ ní Kesarea, àti pé òun tìkára òun ń múra àti padà lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Ẹ jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn olórí yín bá mi sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ìdí ẹ̀sùn tí ẹ fi sun ọkùnrin náà múlẹ̀ níbẹ̀, bí ó bá ní ohun búburú kan tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesarea, ni ọjọ́ kejì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Paulu wá síwájú òun. Nígbà tí Paulu sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá dúró yí i ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Paulu lọ́rùn, tí wọn kò lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. Paulu si wí tí ẹnu rẹ̀ pé, “Èmi kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ kan sì òfin àwọn Júù, tàbí tẹmpili, tàbí sí Kesari.” Ṣùgbọ́n Festu ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Paulu lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?” Paulu sì wí pé, “Mo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kesari níbi tí ó yẹ kí a ṣe ẹjọ́ mí: èmi kò ṣẹ àwọn Júù, bí ìwọ pẹ̀lú ti mọ̀ dájú. Ǹjẹ́ bí mo bá ṣẹ̀, tí ó ṣe pe mo sì ṣe ohun kan tí ó yẹ fún ikú, èmi kò kọ̀ láti kú, ṣùgbọ́n bí kò bá sí òtítọ́ kan nínú ẹ̀sùn tí àwọn Júù yìí fi mi sùn sí, ẹnìkan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fà mí lé wọn lọ́wọ́. Mo fi ọ̀ràn mi lọ Kesari.” Lẹ́yìn tí Festu ti bá àjọ ìgbìmọ̀ sọ̀rọ̀, ó dáhùn pe, “Ìwọ ti fi ọ̀ràn rẹ lọ Kesari. Ní ọ̀dọ̀ Kesari ni ìwọ ó lọ!” Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Agrippa ọba, àti Bernike sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesarea láti kí Festu. Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Festu mú ọ̀ràn Paulu wá síwájú ọba, wí pé, “Feliksi fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú túbú. Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerusalẹmu, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú. “Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi, kí ẹni tí a fi sùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri ààyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn. Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kejì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá. Nígbà tí àwọn olùfisùn náà dìde, wọn kò ka ọ̀ràn búburú irú èyí tí mo rò sí i lọ́rùn. Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jesu kan tí o tí kú, tí Paulu tẹnumọ́ pé ó wà láààyè. Bí èmi kò sì tí mọ̀ bí a tí ń ṣe ìwádìí nǹkan wọ̀nyí, mo bí i lérè pé ṣe ó ń fẹ́ lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu fi ọ̀ràn rẹ lọ Augustu, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pe kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Kesari.” Agrippa wí fún Festu pé, “Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkára mi.” Ó sì wí pé, “Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ.”