Skip to content
Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Iṣe Apo 23:6YBCV(Bibeli Mimọ)

Ṣugbọn nigbati Paulu ṣakiyesi pe, apakan wọn jẹ Sadusi, apakan si jẹ Farisi, o kigbe ni igbimọ pe, Ará, Farisi li emi, ọmọ Farisi: nitori ireti ati ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ.

Iṣe Apo 23:6BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”

Iṣe Apo 23:6YCE(Yoruba Bible)

Nígbà tí Paulu mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi ni apá kan ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ìgbìmọ̀, àtipé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Farisi ni àwọn mìíràn, ó kígbe pé, “Ẹ̀yin ará, Farisi ni mí. Farisi ni àwọn òbí mi. Nítorí ìrètí wa pé àwọn òkú yóo jí dìde ni wọ́n ṣe mú mi wá dáhùn ẹjọ́.”