Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 23:3YBCV(Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Paulu wi fun u pe, Ọlọrun yio lù ọ, iwọ ogiri ti a kùn li ẹfun: iwọ joko lati dajọ mi ni gẹgẹ bi ofin, iwọ si pè ki a lù mi li òdi si ofin?
Iṣe Apo 23:3BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!”
Iṣe Apo 23:3YCE(Yoruba Bible)
Paulu wá sọ fún un pé, “Ọlọrun yóo lù ọ́. Ìwọ ògiri tí wọ́n kùn lẹ́fun lásán yìí! O jókòó sibẹ, ò ń dá mi lẹ́jọ́ lórí Òfin, sibẹ o pa Òfin tì, o ní kí wọ́n lù mí.”