Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 22:3YBCV(Bibeli Mimọ)
Ju li emi iṣe ẹniti a bí ni Tarsu ilu kan ni Kilikia, ṣugbọn ti a tọ́ ni ilu yi, li ẹsẹ Gamalieli, ti a kọ́ gẹgẹ bi lile ofin awọn baba wa, ti mo si jẹ onitara fun Ọlọrun ani gẹgẹ bi gbogbo nyin ti ri li oni.
Iṣe Apo 22:3BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tarsu ìlú kan ní Kilikia, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gamalieli ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì ní ìtara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní.
Iṣe Apo 22:3YCE(Yoruba Bible)
“Juu ni mí, Tasu ní ilẹ̀ Silisia la gbé bí mi. Ní ìlú yìí ni a gbé tọ́ mi dàgbà. Ilé-ìwé Gamalieli ni mo lọ, ó sì kọ́ mi dáradára nípa Òfin ìbílẹ̀ wa. Mo ní ìtara fún Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti ní lónìí.