Iṣe Apo 22:21-22 - Compare All Versions
Iṣe Apo 22:21-22 YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Mã lọ: nitori emi ó rán ọ si awọn Keferi lokere réré. Nwọn si fi etí si i titi de ọ̀rọ yi, nwọn si gbé ohùn wọn soke wipe, Ẹ mu irú eyiyi kuro li aiye: nitori kò yẹ ki o wà lãye.
Iṣe Apo 22:21-22 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, ‘Máa lọ; nítorí èmi ó rán ọ sí àwọn aláìkọlà lókèèrè réré.’ ” Wọ́n sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Paulu títí tí ó fi sọ ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà yìí ni wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì kígbe wí pé, “Ẹ mu ẹni yìí kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láààyè!”
Iṣe Apo 22:21-22 YCE (Yoruba Bible)
Ṣugbọn Oluwa sọ fún mi pé, ‘Bọ́ sọ́nà, nítorí n óo rán ọ lọ sí ọ̀nà jíjìn, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu.’ ” Àwọn eniyan fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí gbolohun yìí fi jáde. Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbolohun yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ rẹ́ kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè!”