Iṣe Apo 21:27-40
Iṣe Apo 21:27-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ọjọ meje si fẹrẹ pé, ti awọn Ju ti o ti Asia wa ri i ni tẹmpili, nwọn rú gbogbo awọn enia soke, nwọn nawọ́ mu u. Nwọn nkigbe wipe, Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbà wa: Eyi li ọkunrin na, ti nkọ́ gbogbo enia nibigbogbo lòdi si awọn enia, ati si ofin, ati si ibi yi: ati pẹlu o si mu awọn ara Hellene wá si tẹmpili, o si ti ba ibi mimọ́ yi jẹ. Nitori nwọn ti ri Trofimu ará Efesu pẹlu rẹ̀ ni ilu, ẹniti nwọn ṣebi Paulu mu wá sinu tẹmpili. Gbogbo ilu si rọ́, awọn enia si sure jọ: nwọn si mu Paulu, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu tẹmpili: lojukanna a si tì ilẹkun. Bi nwọn si ti nwá ọ̀na ati pa a, ìhin de ọdọ olori ẹgbẹ ọmọ-ogun pe, gbogbo Jerusalemu dàrú. Lojukanna o si ti mu awọn ọmọ-ogun ati awọn balogun ọrún, o si sure sọkalẹ tọ̀ wọn lọ: nigbati nwọn si ri olori ogun ati awọn ọmọ-ogun, nwọn dẹkun lilu Paulu. Nigbana li olori ogun sunmọ wọn, o si mu u, o paṣẹ pe ki a fi ẹ̀wọn meji dè e; o si bère ẹniti iṣe, ati ohun ti o ṣe. Awọn kan nkígbe ohun kan, awọn miran nkigbe ohun miran ninu awujọ: nigbati kò si le mọ̀ eredi irukerudò na dajudaju, o paṣẹ ki nwọn ki o mu u lọ sinu ile-olodi. Nigbati o si de ori atẹgùn, gbigbé li a gbé e soke lọwọ awọn ọmọ-ogun nitori iwa-ipa awọn enia. Nitori ọ̀pọ enia gbátì i, nwọn nkigbe pe, Mu u kuro. Bi nwọn si ti fẹrẹ imu Paulu wọ̀ inu ile-olodi lọ, o wi fun olori-ogun pe, Emi ha gbọdọ ba ọ sọ̀rọ? O si dahùn wipe, Iwọ mọ̀ ède Hellene ifọ̀? Iwọ ha kọ́ ni ara Egipti nì, ti o ṣọ̀tẹ ṣaju ọjọ wọnyi, ti o si ti mu ẹgbaji ọkunrin ninu awọn ti iṣe apania lẹhin lọ si iju? Ṣugbọn Paulu si wipe, Ju li emi iṣe, ara Tarsu ilu Kilikia, ọlọ̀tọ ilu ti kì iṣe ilu lasan kan, emi si bẹ ọ, bùn mi lãye lati ba awọn enia sọrọ. Nigbati o si ti bùn u lãye, Paulu duro lori atẹgùn, o si juwọ́ si awọn enia. Nigbati nwọn si dakẹrọrọ o ba wọn sọrọ li ède Heberu, wipe
Iṣe Apo 21:27-40 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ọjọ́ meje náà fẹ́rẹ̀ pé, àwọn Juu láti Esia rí Paulu ninu Tẹmpili. Wọ́n bá ké ìbòòsí láàrin gbogbo èrò, wọ́n sì dọwọ́ bo Paulu, wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ gbani o! Ọkunrin tí ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo láti lòdì sí orílẹ̀-èdè wa ati Òfin Mose ati ilé yìí nìyí. Ó tún mú àwọn Giriki wọ inú Tẹmpili; ó wá sọ ibi mímọ́ yìí di àìmọ́.” Wọ́n sọ báyìí nítorí pé wọ́n ti kọ́kọ́ rí Tirofimọsi ará Efesu pẹlu Paulu láàrin ìlú, wọ́n wá ṣebí Paulu mú un wọ inú Tẹmpili ni. Gbogbo ìlú bá dàrú. Àwọn eniyan ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ Paulu. Wọ́n bá mú un, wọ́n wọ́ ọ jáde kúrò ninu Tẹmpili. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá ti gbogbo ìlẹ̀kùn. Wọ́n fẹ́ pa á ni ìròyìn bá kan ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. Lójú kan náà ó bá mú àwọn ọmọ-ogun pẹlu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó sáré lọ bá wọn. Nígbà tí àwọn èrò rí ọ̀gágun ati àwọn ọmọ-ogun, wọ́n dáwọ́ dúró, wọn kò lu Paulu mọ́. Ọ̀gágun bá súnmọ́ Paulu, ó mú un, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é. Ó wá wádìí ẹni tí ó jẹ́ ati ohun tí ó ṣe. Àwọn kan ninu èrò ń sọ nǹkankan; àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. Nígbà tí ọ̀gágun náà kò lè mọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà nítorí ariwo èrò, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun. Nígbà tí wọ́n dé àtẹ̀gùn ilé, gbígbé ni àwọn ọmọ-ogun níláti gbé Paulu wọlé nítorí ojú àwọn èrò ti ranko. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé wọn, tí wọn ń kígbe pé, “Ẹ pa á!” Bí wọ́n ti fẹ́ mú Paulu wọ inú àgọ́ ọmọ-ogun, ó sọ fún ọ̀gágun pé, “Ṣé kò léèwọ̀ bí mo bá bá ọ sọ nǹkankan?” Ọ̀gágun wá bi í léèrè pé, “O gbọ́ èdè Giriki? Ìyẹn ni pé kì í ṣe ìwọ ni ará Ijipti tí ó dá rúkèrúdò sílẹ̀ láìpẹ́ yìí, tí ó kó ẹgbaaji (4000) àwọn agúnbẹ lẹ́yìn lọ sí aṣálẹ̀?” Paulu dáhùn ó ní, “Juu ni mí, ará Tasu ní ilẹ̀ Silisia. Ọmọ ìlú tí ó lókìkí ni mí. Gbà mí láàyè kí n bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀.” Nígbà tí ó gbà fún un, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó gbọ́wọ́ sókè kí àwọn eniyan lè dákẹ́. Nígbà tí wọ́n dákẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Heberu.
Iṣe Apo 21:27-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Asia wá rí i ni tẹmpili, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un. Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbà wá: Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn ènìyàn, àti sí òfin, àti sí ibí yìí: àti pẹ̀lú ó sì mú àwọn ará Giriki wá sínú tẹmpili, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.” Nítorí wọ́n tí rí Tirofimu ará Efesu pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Paulu mú wá sínú tẹmpili. Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdò, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Paulu, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹmpili: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn. Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu. Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe. Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun. Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!” Bí wọ́n sì tí fẹ́rẹ̀ mú Paulu wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó wí fún olórí ogun pé, “Èmi ha lè bá ọ sọ̀rọ̀ bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ìwọ mọ èdè Giriki bí? Ìwọ ha kọ ní ara Ejibiti náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ sí ijù?” Ṣùgbọ́n Paulu sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tarsu ìlú Kilikia, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi síbẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!” Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́ rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wí pé