Iṣe Apo 2:6-21
Iṣe Apo 2:6-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si gbọ iró yi, ọ̀pọlọpọ enia pejọ, nwọn si damu, nitoriti olukuluku gbọ́ nwọn nsọ̀rọ li ède rẹ̀. Hà si ṣe gbogbo wọn, ẹnu si yà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Wo o, ara Galili ki gbogbo awọn ti nsọ̀rọ wọnyi iṣe? Ẽha si ti ṣe ti awa fi ngbọ́ olukuluku li ede wa ninu eyiti a bí wa? Awọn ará Partia, ati Media, ati Elamu, ati awọn ti ngbé Mesopotamia, Judea, ati Kappadokia, Pontu, ati Asia, Frigia, ati Pamfilia, Egipti, ati ẹkùn Libia niha Kirene, ati awọn atipo Romu, awọn Ju ati awọn alawọṣe Ju, Awọn ara Krete ati Arabia, awa gbọ́ nwọn nsọ̀rọ iṣẹ iyanu nla Ọlọrun li ède wa. Hà si ṣe gbogbo wọn, o si rú wọn lojú, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili a le mọ̀ eyi si? Ṣugbọn awọn ẹlomiran nṣẹ̀fẹ nwọn si wipe, Awọn ọkunrin wọnyi kún fun waini titun. Ṣugbọn Peteru dide duro pẹlu awọn mọkanla iyokù, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o si wi fun wọn gbangba pe, Ẹnyin enia Judea, ati gbogbo ẹnyin ti ngbé Jerusalemu, ki eyiyi ki o yé nyin, ki ẹ si fetísi ọ̀rọ mi: Nitori awọn wọnyi kò mutiyó, bi ẹnyin ti fi pè; wakati kẹta ọjọ sá li eyi. Ṣugbọn eyi li ọ̀rọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joeli wá pe; Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin-ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá: Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obinrin li emi o tú ninu Ẹmí mi jade li ọjọ wọnni; nwọn o si ma sọtẹlẹ: Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn loke li ọrun, ati àmi nisalẹ lori ilẹ: ẹ̀jẹ, ati iná, ati ríru ẹ̃fin; A o sọ õrùn di òkunkun, ati oṣupa di ẹ̀jẹ, ki ọjọ nla afiyesi Oluwa ki o to de: Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba pè orukọ Oluwa, a o gbà a là.
Iṣe Apo 2:6-21 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró yìí, àwọn eniyan rọ́ wá. Ẹnu yà wọ́n nítorí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọ́ tí wọn ń sọ èdè tirẹ̀. Èyí dà wọ́n láàmú, ó sì yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ní, “Ṣebí ará Galili ni gbogbo àwọn tí ó ń sọ̀rọ̀ wọnyi? Kí ló dé tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa fi gbọ́ tí wọn ń sọ èdè abínibí rẹ̀? Ati ará Patia, ati ará Media ati ará Elamu; àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ Mesopotamia, ilẹ̀ Judia ati ilẹ̀ Kapadokia; ilẹ̀ Pọntu, ilẹ̀ Esia, ilẹ̀ Firigia ati ilẹ̀ Pamfilia; ilẹ̀ Ijipti ati agbègbè Libia lẹ́bàá Kirene; àwọn àlejò láti ìlú Romu, àwọn Juu ati àwọn aláwọ̀ṣe ẹ̀sìn Juu; àwọn ará Kirete ati àwọn ará Arabia, gbogbo wa ni a gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn iṣẹ́ ńlá Ọlọrun ní oríṣìíríṣìí èdè wa.” Ìdààmú bá gbogbo àwọn eniyan, ó pá wọn láyà. Wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ èyí?” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ní, “Wọ́n ti mu ọtí yó ni!” Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni. Ṣugbọn ohun tí Joẹli, wolii Ọlọrun ti sọ wá ṣẹ lónìí, tí ó wí pé, ‘Ọlọrun sọ pé, “Nígbà tí ó bá di àkókò ìkẹyìn, n óo tú Ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin yóo sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọdọmọkunrin yín yóo rí ìran, àwọn àgbà yín yóo sì lá àlá. Àní, ní àkókò náà, n óo tú Ẹ̀mí mi sórí àwọn ẹrukunrin mi ati sí orí àwọn ẹrubinrin mi, àwọn náà yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. N óo fi ohun ìyanu hàn lókè ọ̀run, ati ohun abàmì lórí ilẹ̀ ayé; ẹ̀jẹ̀, ati iná, ìkùukùu ati èéfín. Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo di ẹ̀jẹ̀, kí ó tó di ọjọ́ ńlá tí ó lókìkí, ọjọ́ Oluwa. Ní ọjọ́ náà gbogbo ẹni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” ’
Iṣe Apo 2:6-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀. Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Galili kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́? Èéha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀? Àwọn ará Partia, àti Media, àti Elamu; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamia, Judea, àti Kappadokia, Pọntu àti Asia. Frigia, àti pamfilia, Ejibiti, àti agbègbè Libia níhà Kirene; àti àwọn àtìpó Romu, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù (àti àwọn Júù àti àwọn tí a ti ipa ẹ̀sìn sọ di Júù); àwọn ará Krete àti Arabia; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì wárìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?” Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn ń ṣẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì tuntun”. Nígbà náà ni Peteru dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin; kí ẹ sì fetísí ọ̀rọ̀ mi. Àwọn wọ̀nyí kò mu ọtí yó, bí ẹ̀yin tí rò ó; wákàtí kẹta ọjọ́ sá à ni èyí. Bẹ́ẹ̀ kọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ti a ti sọ láti ẹnu wòlíì Joeli wá pé: “Ọlọ́run wí pé, ‘Ní ìkẹyìn ọjọ́, Èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí jáde sára ènìyàn gbogbo, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò sì máa ríran, àwọn arúgbó yín yóò sì máa lá àlá; Àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi obìnrin, ni Èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mi jáde ni ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀; Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run, àti àwọn ààmì nísàlẹ̀ ilẹ̀; ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín; A ó sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé. Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’