Iṣe Apo 2:46-47
Iṣe Apo 2:46-47 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si nfi ọkàn kan duro li ojojumọ́ ninu tẹmpili ati ni bibu akara ni ile, nwọn nfi inu didùn ati ọkàn kan jẹ onjẹ wọn. Nwọn nyin Ọlọrun, nwọn si ni ojurere lọdọ enia gbogbo. Oluwa si nyàn kún wọn li ojojumọ awọn ti a ngbalà.
Pín
Kà Iṣe Apo 2Iṣe Apo 2:46-47 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n ń fi ọkàn kan lọ sí Tẹmpili lojoojumọ. Wọ́n jọ ń jẹun láti ilé dé ilé. Wọ́n jọ ń jẹun pẹlu ayọ̀ ati pẹlu ọkàn kan. Wọ́n ń fi ìyìn fún Ọlọrun. Gbogbo àwọn eniyan ni ó fẹ́ràn wọn. Lojoojumọ ni àwọn tí wọ́n rí ìgbàlà ń dara pọ̀ mọ́ wọn.
Pín
Kà Iṣe Apo 2Iṣe Apo 2:46-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹmpili. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn. Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojúrere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà.
Pín
Kà Iṣe Apo 2