Iṣe Apo 2:42-46 - Compare All Versions

Iṣe Apo 2:42-46 YBCV (Bibeli Mimọ)

Nwọn si duro ṣinṣin ninu ẹkọ́ awọn aposteli, ati ni idapọ, ni bibu akara ati ninu adura. Ẹ̀rù si ba gbogbo ọkàn: iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi pipọ li a ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe. Gbogbo awọn ti o si gbagbọ́ wà ni ibikan, nwọn ni ohun gbogbo ṣọkan; Nwọn si ntà ohun ini ati ẹrù wọn, nwọn si npín wọn fun olukuluku, gẹgẹ bi ẹnikẹni ti ṣe alaini. Nwọn si nfi ọkàn kan duro li ojojumọ́ ninu tẹmpili ati ni bibu akara ni ile, nwọn nfi inu didùn ati ọkàn kan jẹ onjẹ wọn.

Iṣe Apo 2:42-46 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn aposteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà. Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe. Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn; Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní sí. Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹmpili. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn.

Iṣe Apo 2:42-46 YCE (Yoruba Bible)

Wọ́n ń fi tọkàntọkàn kọ́ ẹ̀kọ́ tí àwọn aposteli ń kọ́ wọn; wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n jọ ń jẹun; wọ́n jọ ń gbadura. Ẹ̀rù àwọn onigbagbọ wá ń ba gbogbo eniyan. Ọpọlọpọ ni iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe. Gbogbo àwọn onigbagbọ wà ní ibìkan náà. Wọ́n jọ ní ohun gbogbo ní àpapọ̀. Wọ́n ta gbogbo ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì pín owó tí wọ́n rí láàrin ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ṣe aláìní sí. Wọ́n ń fi ọkàn kan lọ sí Tẹmpili lojoojumọ. Wọ́n jọ ń jẹun láti ilé dé ilé. Wọ́n jọ ń jẹun pẹlu ayọ̀ ati pẹlu ọkàn kan.