Iṣe Apo 2:39-42
Iṣe Apo 2:39-42 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè. Ati ọ̀rọ pupọ miran li o fi njẹri ti o si nfi ngbà wọn niyanju wipe, Ẹ gbà ara nyin là lọwọ iran arekereke yi. Nitorina awọn ti o si fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ rẹ̀ a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn. Nwọn si duro ṣinṣin ninu ẹkọ́ awọn aposteli, ati ni idapọ, ni bibu akara ati ninu adura.
Iṣe Apo 2:39-42 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ẹ̀yin ni a ṣe ìlérí yìí fún, ati àwọn ọmọ yín ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn; a ṣe é fún gbogbo ẹni tí Oluwa Ọlọrun wa bá pè.” Ó tún bá wọn sọ̀rọ̀ pupọ, ó ń rọ̀ wọ́n gidigidi, pé, “Ẹ gba ara yín kúrò ninu ìyà tí ìran burúkú yìí yóo jẹ.” A ṣe ìrìbọmi fún àwọn tí wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà. Ní ọjọ́ náà àwọn ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni a kà kún ọmọ ìjọ. Wọ́n ń fi tọkàntọkàn kọ́ ẹ̀kọ́ tí àwọn aposteli ń kọ́ wọn; wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n jọ ń jẹun; wọ́n jọ ń gbadura.
Iṣe Apo 2:39-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.” Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.” Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamitiisi wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkàn kún wọn. Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn aposteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà.