Iṣe Apo 19:11-12
Iṣe Apo 19:11-12 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun fún Paulu lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan fi ń mú ìdikù tabi aṣọ-iṣẹ́ tí ó ti kan ara Paulu, lọ fi lé àwọn aláìsàn lára, àìsàn wọn sì ń fi wọ́n sílẹ̀, ẹ̀mí burúkú sì ń jáde kúrò lára wọn.
Iṣe Apo 19:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu, tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.
Iṣe Apo 19:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun si ti ọwọ́ Paulu ṣe iṣẹ aṣẹ akanṣe, Tobẹ̃ ti a fi nmu gèle ati ibantẹ́ ara rẹ̀ tọ̀ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn.