Fò sí àkóónú

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Iṣe Apo 19:1-2YBCV(Bibeli Mimọ)

O si ṣe, nigbati Apollo ti wà ni Korinti, ti Paulu kọja lọ niha ẹkùn oke, o wá si Efesu: o si ri awọn ọmọ-ẹhin kan; O wi fun wọn pe, Ẹnyin ha gbà Ẹmí Mimọ́ na nigbati ẹnyin gbagbọ́? Nwọn si wi fun u pe, Awa kò gbọ́ rara bi Ẹmí Mimọ́ kan wà.

Iṣe Apo 19:1-2BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nígbà ti Apollo wà ni Kọrinti, ti Paulu kọjá lọ sí apá òkè ìlú, ó sì wá sí Efesu, o sì rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kan; o wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ha gba Ẹ̀mí Mímọ́ náà nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò gbọ́ rárá pé Ẹ̀mí Mímọ́ kan wà.”

Iṣe Apo 19:1-2YCE(Yoruba Bible)

Nígbà tí Apolo wà ní Kọrinti, Paulu gba ọ̀nà ilẹ̀ la àwọn ìlú tí ó wà ní àríwá Antioku kọjá títí ó fi dé Efesu. Ó rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu mélòó kan níbẹ̀. Ó bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́ nígbà tí ẹ gba Jesu gbọ́?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o! A kò tilẹ̀ gbọ́ ọ rí pé nǹkankan wà tí ń jẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.”