Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 18:5YBCV(Bibeli Mimọ)
Nigbati Sila on Timotiu si ti Makedonia wá, ọrọ na ká Paulu lara, o nfi hàn, o sọ fun awọn Ju pe, Jesu ni Kristi na.
Iṣe Apo 18:5BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà.
Iṣe Apo 18:5YCE(Yoruba Bible)
Nígbà tí Sila ati Timoti dé láti Masedonia, Paulu wá fi gbogbo àkókò rẹ̀ sílẹ̀ fún iwaasu, ó ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu pé Jesu ni Mesaya.