Fò sí àkóónú

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Iṣe Apo 16:37YBCV(Bibeli Mimọ)

Ṣugbọn Paulu wi fun wọn pe, Nwọn lù wa ni gbangba, nwọn si sọ wa sinu tubu li aijẹbi, awa ẹniti iṣe ara Romu: nisisiyi nwọn si fẹ ti wa jade nikọ̀kọ? agbẹdọ; ṣugbọn ki awọn tikarawọn wá mu wa jade.

Iṣe Apo 16:37BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ṣùgbọ́n Paulu wí fún wọn pé, “Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bi, àwa ẹni tí ì ṣe ara Romu. Ṣe nísinsin yìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀? Rara! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkára wọn wá mú wa jáde!”

Iṣe Apo 16:37YCE(Yoruba Bible)

Ṣugbọn Paulu sọ fún wọn pé, “Wọ́n nà wá ní gbangba láì ká ẹ̀bi mọ́ wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wá. Wọ́n sọ wá sẹ́wọ̀n, wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀. Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá kó wa jáde.”