Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 16:13YBCV(Bibeli Mimọ)
Lọjọ isimi, awa si jade lọ si ẹhin odi ilu na, lẹba odò kan, nibiti a rò pe ibi adura wà; awa si joko, a si ba awọn obinrin ti o pejọ sọrọ.
Iṣe Apo 16:13BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bàá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókòó, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ sọ̀rọ̀.
Iṣe Apo 16:13YCE(Yoruba Bible)
Ní Ọjọ́ Ìsinmi a jáde lọ sẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá odò, níbi tí a rò pé a óo ti rí ibi tí wọn máa ń gbadura. A bá jókòó, a bá àwọn obinrin tí ó péjọ níbẹ̀ sọ̀rọ̀.