Iṣe Apo 16:1-3
Iṣe Apo 16:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wá si Derbe on Listra: si kiyesi i, ọmọ-ẹhin kan wà nibẹ̀, ti a npè ni Timotiu, ọmọ obinrin kan ti iṣe Ju, ti o gbagbọ́; ṣugbọn Hellene ni baba rẹ̀: Ẹniti a rohin rẹ̀ rere lọdọ awọn arakunrin ti o wà ni Listra ati Ikonioni. On ni Paulu fẹ ki o ba on lọ; o si mu u, o si kọ ọ ni ilà, nitori awọn Ju ti o wà li àgbegbe wọnni: nitori gbogbo wọn mọ̀ pe, Hellene ni baba rẹ̀.
Iṣe Apo 16:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Paulu dé Dabe ati Listira. Onigbagbọ kan tí ń jẹ́ Timoti wà níbẹ̀. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Juu tí ó gba Jesu gbọ́; ṣugbọn Giriki ni baba rẹ̀. Àwọn arakunrin ní Listira ati Ikoniomu ròyìn Timoti yìí dáradára. Òun ni ó wu Paulu láti mú lọ sí ìrìn-àjò rẹ̀, nítorí náà, ó mú un, ó kọ ọ́ nílà nítorí àwọn Juu tí ó wà ní agbègbè ibẹ̀; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n mọ̀ pé Giriki ni baba rẹ̀.
Iṣe Apo 16:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wá sí Dabe àti Lysra: sí kíyèsi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Timotiu, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Giriki ní baba rẹ̀. Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lysra àti Ikoniomu. Òun ni Paulu fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbègbè wọ̀nyí: nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Giriki ni baba rẹ̀.