Iṣe Apo 15:6-12
Iṣe Apo 15:6-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati awọn aposteli ati awọn àgbagbà pejọ lati gbìmọ ọ̀ran yi. Nigbati iyàn si di pipọ, Peteru dide, o si wi fun wọn pe, Ará, ẹnyin mọ̀ pe, lati ibẹrẹ Ọlọrun ti yàn ninu nyin, ki awọn Keferi ki o le gbọ́ ọ̀rọ ihinrere li ẹnu mi, ki nwọn si gbagbọ́. Ati Ọlọrun, ti iṣe olumọ-ọkàn, o jẹ wọn li ẹrí, o nfun wọn li Ẹmí Mimọ́, gẹgẹ bi awa: Kò si fi iyatọ si ãrin awa ati awọn, o nfi igbagbọ́ wẹ̀ wọn li ọkàn mọ́. Njẹ nitorina ẽṣe ti ẹnyin o fi dán Ọlọrun wò, lati fi àjaga bọ̀ awọn ọmọ-ẹhin li ọrùn, eyiti awọn baba wa ati awa kò le rù? Ṣugbọn awa gbagbọ́ pe nipa ore-ọfẹ Oluwa Jesu awa ó là, gẹgẹ bi awọn. Gbogbo ajọ si dakẹ, nwọn si fi eti si Barnaba on Paulu, ti nwọn nròhin iṣẹ aṣẹ ati iṣẹ àmi ti Ọlọrun ti ti ọwọ́ wọn ṣe lãrin awọn Keferi.
Iṣe Apo 15:6-12 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà bá péjọ láti rí sí ọ̀rọ̀ yìí. Àríyànjiyàn pupọ ni ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Peteru bá dìde, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ̀yin gan-an mọ̀ pé ní àtijọ́ Ọlọrun yàn mí láàrin yín pé láti ẹnu mi ni àwọn tí kì í ṣe Juu yóo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere, kí wọ́n lè gba Jesu gbọ́. Ọlọrun olùmọ̀ràn ọkàn fún wọn ní ìwé ẹ̀rí nígbà tí ó fún wọn ní Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti fún wa. Kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàrin àwa ati àwọn; ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nítorí wọ́n gba Jesu gbọ́. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ní ṣe tí ẹ fi fẹ́ dán Ọlọrun wò, tí ẹ fẹ́ gbé àjàgà tí àwọn baba wa ati àwa náà kò tó rù, rù àwọn ọmọ-ẹ̀yìn? A gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Jesu Oluwa ni a fi gbà wá là, gẹ́gẹ́ bí a ti fi gba àwọn náà là.” Ńṣe ni gbogbo àwùjọ dákẹ́ jẹ́ẹ́. Wọ́n wá fetí sílẹ̀ sí ohun tí Banaba ati Paulu níí sọ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu.
Iṣe Apo 15:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn aposteli àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí. Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Peteru dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìnrere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́. Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olùmọ̀-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa. Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárín àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́. Ǹjẹ́ nítorí náà èéṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù? Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jesu àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.” Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi etí sí Barnaba àti Paulu, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrín àwọn aláìkọlà.