Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 15:22YBCV(Bibeli Mimọ)
Nigbana li o tọ́ loju awọn aposteli, ati awọn àgbagbà pẹlu gbogbo ijọ, lati yàn enia ninu wọn, ati lati ran wọn lọ si Antioku pẹlu Paulu on Barnaba: Juda ti a npè apele rẹ̀ ni Barsaba, ati Sila, ẹniti o l'orukọ ninu awọn arakunrin.
Iṣe Apo 15:22BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.
Iṣe Apo 15:22YCE(Yoruba Bible)
Àwọn aposteli ati àwọn àgbà ìjọ pẹlu gbogbo ìjọ wá pinnu láti yan àwọn eniyan láàrin wọn, láti rán lọ sí Antioku pẹlu Paulu ati Banaba. Wọ́n bá yan Juda tí à ń pè ní Basaba ati Sila, tí wọn jẹ́ aṣaaju láàrin àwọn onigbagbọ.