Iṣe Apo 14:1-18
Iṣe Apo 14:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, ni Ikonioni, nwọn jumọ wọ̀ inu sinagogu awọn Ju lọ, nwọn si sọrọ tobẹ̃, ti ọ̀pọlọpọ awọn Ju ati awọn Hellene gbagbọ́. Ṣugbọn awọn alaigbagbọ́ Ju rú ọkàn awọn Keferi soke, nwọn si rọ̀ wọn si awọn arakunrin na. Nitorina nwọn gbe ibẹ̀ pẹ, nwọn nfi igboiya sọrọ ninu Oluwa, ẹniti o jẹri si ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, o si nyọnda ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu mã ti ọwọ́ wọn ṣe. Ṣugbọn ọ̀pọ enia ilu na pin meji: apakan si dàpọ mọ́ awọn Ju, apakan si dàpọ mọ́ awọn aposteli. Bi awọn Keferi, ati awọn Ju pẹlu awọn olori wọn ti fẹ kọlù wọn lati ṣe àbuku si wọn, ati lati sọ wọn li okuta, Nwọn mọ̀, nwọn si sá lọ si Listra ati Derbe ilu Likaonia, ati si àgbegbe ti o yiká: Nibẹ̀ ni nwọn si nwasu ihinrere. Ọkunrin kan si joko ni Listra, ẹniti ẹsẹ rẹ̀ kò mokun, arọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti kò rìn ri. Ọkunrin yi gbọ́ bi Paulu ti nsọ̀rọ: ẹni, nigbati o tẹjumọ́ ọ, ti o si ri pe, o ni igbagbọ́ fun imularada, O wi fun u li ohùn rara pe, Dide duro ṣanṣan li ẹsẹ rẹ. O si nfò soke o si nrìn. Nigbati awọn enia si ri ohun ti Paulu ṣe, nwọn gbé ohùn wọn soke li ède Likaonia, wipe, Awọn oriṣa sọkalẹ tọ̀ wa wá ni àwọ enia. Nwọn si pè Barnaba ni Jupiteri ati Paulu ni Herme nitori on li olori ọ̀rọ isọ. Alufa Jupiteri ti ile oriṣa rẹ̀ wà niwaju ilu wọn, si mu malu ati màriwo wá si ẹnubode, on iba si rubọ pẹlu awọn enia. Ṣugbọn nigbati awọn aposteli Barnaba on Paulu gbọ́, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si sure wọ̀ inu awujọ, nwọn nke rara. Nwọn si nwipe, Ará, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe nkan wọnyi? Enia oniru ìwa kanna bi ẹnyin li awa pẹlu ti a nwasu ihinrere fun nyin, ki ẹnyin ki o yipada kuro ninu ohun asan wọnyi si Ọlọrun alãye, ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn: Ẹni, ni awọn iran ti o ti kọja jọwọ gbogbo orilẹ-ède, lati mã rìn li ọna tiwọn. Ṣugbọn ko fi ara rẹ̀ silẹ li ailẹri, ni ti o nṣe rere, o nfun nyin ni òjo lati ọrun wá, ati akokò eso, o nfi onjẹ ati ayọ̀ kún ọkàn nyin. Diẹ li o kù ki nwọn ki o ma le fi ọ̀rọ wọnyi da awọn enia duro, ki nwọn ki o máṣe rubọ bọ wọn.
Iṣe Apo 14:1-18 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n dé Ikoniomu, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Wọ́n sọ̀rọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ati àwọn Giriki fi gba Jesu gbọ́. Àwọn Juu tí kò gbà pé Jesu ni Mesaya wá gbin èrò burúkú sí ọkàn àwọn tí kì í ṣe Juu, wọ́n rú wọn sókè sí àwọn onigbagbọ. Paulu ati Banaba pẹ́ níbẹ̀. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, ẹ̀rù kò sì bà wọ́n nítorí wọ́n gbójú lé Oluwa tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ti ọwọ́ wọn ṣe. Ìyapa bẹ́ sáàrin àwọn eniyan ninu ìlú; àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn Juu, àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn aposteli. Àwọn Juu ati àwọn tí kì í ṣe Juu pẹlu àwọn ìjòyè wọn dábàá láti ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́, wọ́n fẹ́ sọ wọ́n ní òkúta pa. Nígbà tí àwọn aposteli mọ̀, wọ́n sálọ sí Listira ati Dabe, ìlú meji ní Likaonia, ati àwọn agbègbè wọn. Wọ́n bá ń waasu ìyìn rere níbẹ̀. Ọkunrin kan wà ní ìjókòó ní Listira tí ó yarọ. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí i ni ó ti yarọ, kò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn rí. Ọkunrin yìí fetí sílẹ̀ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀. Paulu wá tẹjú mọ́ ọn lára, ó rí i pé ó ní igbagbọ pé wọ́n lè mú òun lára dá. Ó bá kígbe sókè, ó ní, “Dìde, kí o dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ bí eniyan.” Ni ọkunrin arọ náà bá fò sókè, ó bá ń rìn. Nígbà tí àwọn eniyan rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n kígbe ní èdè Likaonia pé, “Àwọn oriṣa ti di eniyan, wọ́n tọ̀run wá sáàrin wa!” Wọ́n pe Banaba ní Seusi, wọ́n pe Paulu ní Herime nítorí òun ni ó ń ṣe ògbifọ̀. Ní òde kí á tó wọ odi ìlú ni tẹmpili Seusi wà. Baba olórìṣà Seusi bá mú mààlúù ati òdòdó jìngbìnnì, òun ati ọpọlọpọ èrò, wọ́n ń bọ̀ lẹ́nu odi ìlú níbi tí pẹpẹ Seusi wà, wọ́n fẹ́ wá bọ wọ́n. Nígbà tí Banaba aposteli ati Paulu aposteli gbọ́, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bá pa kuuru mọ́ àwọn èrò, wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ̀yin eniyan, kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe irú eléyìí? Eniyan bíi yín ni àwa náà. À ń waasu fun yín pé kí ẹ yipada kúrò ninu àwọn ohun asán wọnyi, kí ẹ sin Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, ati òkun ati ohun gbogbo tí ó wà ninu wọn. Ní ìgbà ayé àwọn tí ó ti kọjá, ó jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n. Sibẹ kò ṣàì fi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fun yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fun yín ní oúnjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.” Pẹlu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, agbára-káká ni wọn kò fi jẹ́ kí àwọn eniyan bọ wọ́n.
Iṣe Apo 14:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sí ṣe, ni Ikoniomu, Paulu àti Barnaba jùmọ̀ wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn Helleni gbàgbọ́, Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà. Nítorí náà Paulu àti Barnaba gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì mu kí iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apá kan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apá kan pẹ̀lú àwọn aposteli. Bí àwọn aláìkọlà, àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olórí wọn ti fẹ́ kọlù wọ́n láti fi àbùkù kàn wọ́n, àti láti sọ wọ́n ní òkúta, wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lysra, àti Dabe, àwọn ìlú Likaonia àti sí agbègbè àyíká. Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere. Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lysra, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí. Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá. Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn. Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Likaonia, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!” Wọn sì pe Barnaba ni Seusi àti Paulu ni Hermesi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ sísọ. Àlùfáà Seusi, ẹni ti ilé òrìṣà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu ibodè láti rú ẹbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn aposteli wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn aposteli Barnaba àti Paulu gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé: “Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìhìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn. Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.” Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rú ẹbọ bọ wọ́n.