Skip to content
Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Iṣe Apo 13:46YBCV(Bibeli Mimọ)

Paulu on Barnaba si sọ laibẹru pe, Ẹnyin li o tọ ki a kọ́ sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun: ṣugbọn bi ẹ ti ta a nù, ẹ sì kà ara nyin si alaiyẹ fun iyè ainipẹkun, wo o, awa yipada sọdọ awọn Keferi.

Iṣe Apo 13:46BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.

Iṣe Apo 13:46YCE(Yoruba Bible)

Paulu ati Banaba wá fi ìgboyà sọ pé, “Ẹ̀yin ni a níláti kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kọ̀ ọ́, tí ẹ kò ka ara yín yẹ fún ìyè ainipẹkun, àwa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu.