Iṣe Apo 13:38 - Compare All Versions

Iṣe Apo 13:38 YBCV (Bibeli Mimọ)

Njẹ ki o yé nyin, ará, pe nipasẹ ọkunrin yi li a nwasu idariji ẹ̀ṣẹ fun nyin

Iṣe Apo 13:38 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín.

Iṣe Apo 13:38-39 YCE (Yoruba Bible)

Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kí ó hàn si yín pé nítorí ẹni yìí ni a ṣe ń waasu ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni yìí ni a fi dá gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ láre, àwọn tí Òfin Mose kò lè dá láre.