Iṣe Apo 13:26-52

Iṣe Apo 13:26-52 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ará, ẹnyin ọmọ iran Abrahamu, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awa li a rán ọ̀rọ igbala yi si. Nitori awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn olori wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ ọ, ati ọ̀rọ awọn woli, ti a nkà li ọjọjọ isimi, kò yé wọn, nwọn mu u ṣẹ ni didajọ rẹ̀ lẹbi. Ati bi nwọn kò tilẹ ti ri ọ̀ran iku si i, sibẹ nwọn rọ̀ Pilatu lati pa a. Bi nwọn si ti mu nkan gbogbo ṣẹ ti a ti kọwe nitori rẹ̀, nwọn si sọ ọ kalẹ kuro lori igi, nwọn si tẹ́ ẹ si ibojì. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú: O si farahàn li ọjọ pipọ fun awọn ti o ba a gòke lati Galili wá si Jerusalemu, awọn ti iṣe ẹlẹri rẹ̀ nisisiyi fun awọn enia. Awa si mu ihinrere wá fun nyin, ti ileri tí a ti ṣe fun awọn baba, Bi Ọlọrun ti mu eyi na ṣẹ fun awọn ọmọ wa, nigbati o ji Jesu dide; bi a si ti kọwe rẹ̀ ninu Psalmu keji pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ. Ati niti pe o ji i dide kuro ninu oku, ẹniti kì yio tun pada si ibajẹ mọ́, o wi bayi pe, Emi ó fun nyin ni ore mimọ́ Dafidi, ti o daju. Nitori o si wi ninu Psalmu miran pẹlu pe, Iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ri idibajẹ. Nitori lẹhin igba ti Dafidi sin iran rẹ̀ tan bi ifẹ Ọlọrun, o sùn, a si tẹ́ ẹ tì awọn baba rẹ̀, o si ri idibajẹ. Ṣugbọn ẹniti Ọlọrun ji dide kò ri idibajẹ. Njẹ ki o yé nyin, ará, pe nipasẹ ọkunrin yi li a nwasu idariji ẹ̀ṣẹ fun nyin: Ati nipa rẹ̀ li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò le da nyin lare ninu ofin Mose. Nitorina ẹ kiyesara, ki eyi ti a ti sọ ninu iwe awọn woli ki o maṣe de ba nyin, pe; Ẹ wo o, ẹnyin ẹlẹgàn, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki a si fẹ nyin kù: nitori emi nṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, iṣẹ ti ẹnyin kò jẹ gbagbọ, bi ẹnikan tilẹ rohìn rẹ̀ fun nyin. Bi nwọn si ti njade, nwọn bẹ̀bẹ pe ki a sọ̀rọ wọnyi fun wọn li ọjọ isimi ti mbọ̀. Nigbati nwọn si jade ni sinagogu, ọ̀pọ ninu awọn Ju ati ninu awọn olufọkansìn alawọṣe tẹle Paulu on Barnaba: awọn ẹniti o ba wọn sọ̀rọ ti nwọn si rọ̀ wọn lati duro ninu ore-ọfẹ Ọlọrun. Li ọjọ isimi keji, gbogbo ilu si fẹrẹ pejọ tan lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun. Ṣugbọn nigbati awọn Ju ri ọ̀pọ enia na, nwọn kún fun owu, nwọn nsọ̀rọ-òdi si ohun ti Paulu nsọ. Paulu on Barnaba si sọ laibẹru pe, Ẹnyin li o tọ ki a kọ́ sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun: ṣugbọn bi ẹ ti ta a nù, ẹ sì kà ara nyin si alaiyẹ fun iyè ainipẹkun, wo o, awa yipada sọdọ awọn Keferi. Bẹ̃li Oluwa sá ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbé ọ kalẹ fun imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le jẹ fun igbala titi de opin aiye. Nigbati awọn Keferi si gbọ́ eyi, nwọn yọ̀, nwọn si yìn ọ̀rọ Ọlọrun logo: gbogbo awọn ti a yàn si ìye ainipẹkun si gbagbọ́. A si tàn ọ̀rọ Oluwa ka gbogbo ẹkùn na. Ṣugbọn awọn Ju rú awọn obinrin olufọkansin ati ọlọlá soke ati awọn àgba ilu na, nwọn si gbe inunibini dide si Paulu on Barnaba, nwọn si ṣí wọn kuro li àgbegbe wọn. Ṣugbọn nwọn gbọ̀n ekuru ẹsẹ wọn si wọn, nwọn si wá si Ikonioni. Awọn ọmọ-ẹhin si kún fun ayọ̀ ati fun Ẹmí Mimọ́.

Iṣe Apo 13:26-52 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ̀yin arakunrin, ìran Abrahamu, ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun, àwa ni a rán iṣẹ́ ìgbàlà yìí sí. Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú. Láìjẹ́ pé wọ́n rí ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú, wọ́n ní kí Pilatu pa á. Nígbà tí wọ́n ti parí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé yóo ṣẹlẹ̀ sí i, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí igi agbelebu, wọ́n tẹ́ ẹ sinu ibojì. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú. Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni ó fi ara hàn fún àwọn tí wọ́n bá a wá sí Jerusalẹmu láti Galili. Àwọn ni ẹlẹ́rìí fún gbogbo eniyan pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. A wá mú ìyìn rere wá fun yín pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa ti ṣẹ, fún àwọn ọmọ wa, nígbà tí ó jí Jesu dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Orin Dafidi keji pé, ‘Ọmọ mi ni ọ́, lónìí yìí ni mo bí ọ.’ Ní ti pé ó jí i dìde kúrò ninu òkú, tí kò pada sí ipò ìdíbàjẹ́ mọ́, ohun tí ó sọ ni pé, ‘Èmi yóo fun yín ní ohun tí mo bá Dafidi pinnu.’ Bẹ́ẹ̀ ni ó tún sọ níbòmíràn pé, ‘O kò ní jẹ́ kí Ẹni ọ̀wọ̀ rẹ mọ ìdíbàjẹ́.’ Nítorí nígbà tí Dafidi ti sin ìran tirẹ̀ tán gẹ́gẹ́ bí ète Ọlọrun, ó sun oorun ikú, ó lọ bá àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ rà nílẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí Ọlọrun jí dìde kò ní ìrírí ìdíbàjẹ́. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kí ó hàn si yín pé nítorí ẹni yìí ni a ṣe ń waasu ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni yìí ni a fi dá gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ láre, àwọn tí Òfin Mose kò lè dá láre. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a kọ sílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii má baà dé ba yín: ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ó yà yín lẹ́nu, kí ẹ sì parun! Nítorí n óo ṣe iṣẹ́ kan ní àkókò yín, tí ẹ kò ní gbàgbọ́ bí ẹnìkan bá ròyìn rẹ̀ fun yín.’ ” Bí Paulu ati Banaba ti ń jáde lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan ń bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n tún pada wá bá wọn sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀. Nígbà tí ìpàdé túká, ọpọlọpọ àwọn Juu ati àwọn tí wọ́n ti di ẹlẹ́sìn àwọn Juu ń tẹ̀lé Paulu ati Banaba. Àwọn òjíṣẹ́ mejeeji yìí tún ń bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n dúró láì yẹsẹ̀ ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi keji, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìlú ni ó péjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa. Nígbà tí àwọn Juu rí ọ̀pọ̀ eniyan, owú mú kí inú bí wọn. Wọ́n bá ń bu ẹnu àtẹ́ lu ohun tí Paulu ń sọ; wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí wọn. Paulu ati Banaba wá fi ìgboyà sọ pé, “Ẹ̀yin ni a níláti kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kọ̀ ọ́, tí ẹ kò ka ara yín yẹ fún ìyè ainipẹkun, àwa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni Oluwa pa láṣẹ fún wa nígbà tí ó sọ pé: ‘Mo ti fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí ìgbàlà mi lè dé òpin ilẹ̀ ayé.’ ” Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu gbọ́, inú wọn dùn. Wọ́n dúpẹ́ fún ọ̀rọ̀ Oluwa. Gbogbo àwọn tí a ti yàn láti ní ìyè ainipẹkun bá gbàgbọ́. Ọ̀rọ̀ Oluwa tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà. Ṣugbọn àwọn Juu rú àwọn gbajúmọ̀ obinrin olùfọkànsìn sókè, ati àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ni wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí Paulu ati Banaba. Wọ́n lé wọn jáde kúrò ní agbègbè wọn. Ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sílẹ̀ bí ẹ̀rí sí àwọn ará ìlú náà, wọ́n bá lọ sí Ikoniomu. Ayọ̀ kún ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sì kún inú wọn.

Iṣe Apo 13:26-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí. Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi. Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á. Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn. “Àwa sì mú ìhìnrere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde: Bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé: “ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ.’ Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé: “ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’ Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé: “ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’ “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́. “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín. Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose. Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé: “ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù; nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín, tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’ ” Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀. Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ péjọ tan láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Paulu ń sọ. Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé: “ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ” Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́. A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà. Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Paulu àti Barnaba, wọ́n sì le wọn kúrò ni agbègbè wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikoniomu. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.