Iṣe Apo 13:1-3
Iṣe Apo 13:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ati Simeoni ti a npè ni Nigeri, ati Lukiu ara Kirene, ati Manaeni, ti a tọ́ pọ̀ pẹlu Herodu tetrarki, ati Saulu. Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si. Nigbati nwọn si ti gbàwẹ, ti nwọn si ti gbadura, ti nwọn si ti gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si rán wọn lọ.
Iṣe Apo 13:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn wolii ati àwọn olùkọ́ wà ninu ìjọ tí ó wà ní Antioku. Ninu wọn ni Banaba ati Simeoni tí wọn ń pè ní Adúláwọ̀ wà, ati Lukiusi ará Kirene, ati Manaeni tí wọ́n jọ tọ́ dàgbà pẹlu Hẹrọdu baálẹ̀, ati Saulu. Bí wọ́n ti jọ ń sin Oluwa, tí wọ́n ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún wọn pé, “Ẹ ya Banaba ati Saulu sọ́tọ̀ fún mi, fún iṣẹ́ pataki kan tí mo ti pè wọ́n fún.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbadura, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn lórí, wọ́n sì ní kí wọ́n máa lọ.
Iṣe Apo 13:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Antioku; Barnaba àti Simeoni tí a ń pè ni Nigeri, àti Lukiu ará Kirene, àti Manaeni (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Herodu tetrarki) àti Saulu. Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Barnaba àti Saulu sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!” Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.