Iṣe Apo 12:5-9
Iṣe Apo 12:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina nwọn pa Peteru mọ́ ninu tubu: ṣugbọn ijọ nfi itara gbadura sọdọ Ọlọrun fun u. Nigbati Herodu iba si mu u jade, li oru na Peteru sùn li arin awọn ọmọ-ogun meji, a fi ẹ̀wọn meji de e, ẹ̀ṣọ́ si wà li ẹnu-ọ̀na, nwọn nṣọ́ tubu na. Si wo o, angẹli Oluwa duro tì i, imọlẹ si mọ́ ninu tubu: nigbati o si lù Peteru pẹ́pẹ li ẹgbẹ o ji i, o ni, Dide kánkan. Ẹwọn rẹ̀ si bọ́ silẹ kuro lọwọ rẹ̀. Angẹli na si wi fun u pe, Di àmure, ki o si so salubàta rẹ. O si ṣe bẹ̃. O si wi fun u pe, Da aṣọ rẹ bora, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. On si jade, o ntọ̀ ọ lẹhin; kò si mọ̀ pe otitọ li ohun na ṣe lati ọwọ́ angẹli na wá; ṣugbọn o ṣebi on wà li ojuran.
Iṣe Apo 12:5-9 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n bá sọ Peteru sẹ́wọ̀n, ṣugbọn gbogbo ìjọ ń fi tọkàntọkàn gbadura sí Ọlọrun nítorí rẹ̀. Ní òru, mọ́jú ọjọ́ tí Hẹrọdu ìbá mú Peteru wá fún ìdájọ́, Peteru sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun meji, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é; àwọn ọmọ-ogun kan sì tún wà lẹ́nu ọ̀nà, tí wọn ń ṣọ́nà. Angẹli Oluwa kan bá yọ dé, ìmọ́lẹ̀ sì tàn ninu ilé náà. Angẹli náà bá rọra lu Peteru lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ní, “Dìde kíá.” Àwọn ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi de Peteru bá yọ bọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, Angẹli náà sọ fún un pé, “Di ìgbànú rẹ, sì wọ sálúbàtà rẹ.” Peteru bá ṣe bí angẹli náà ti wí. Angẹli yìí tún sọ fún un pé, “Da aṣọ rẹ bora, kí o máa tẹ̀lé mi.” Ni Peteru bá tẹ̀lé e jáde. Kò mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tí ó ti ọwọ́ angẹli náà ṣẹlẹ̀, ó ṣebí àlá ni.
Iṣe Apo 12:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un. Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru. Angẹli náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Peteru sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!” Peteru sì jáde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ angẹli náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe bí òun wà lójú ìran.