Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 12:17YBCV(Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn o juwọ́ si wọn pe ki nwọn ki o dakẹ, o si ròhin fun wọn bi Oluwa ti mu on jade kuro ninu tubu. O si wipe, Ẹ lọ isọ nkan wọnyi fun Jakọbu, ati awọn arakunrin. Nigbati o si jade, o lọ si ibomiran.
Iṣe Apo 12:17BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé, “Ẹ ro èyí fún Jakọbu àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn.
Iṣe Apo 12:17YCE(Yoruba Bible)
Ó bá fi ọwọ́ ṣe àmì sí wọn kí wọ́n dákẹ́; ó ròyìn fún wọn bí Oluwa ti ṣe mú òun jáde kúrò lẹ́wọ̀n. Ó ní kí wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jakọbu ati fún àwọn arakunrin yòókù. Ó bá jáde, ó lọ sí ibòmíràn.