Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Iṣe Apo 10:28YBCV(Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ bi o ti jẹ ẽwọ̀ fun ẹniti iṣe Ju, lati ba ẹniti iṣe ara ilẹ miran kẹgbẹ, tabi lati tọ̀ ọ wá; ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mi pe, ki emi ki o máṣe pè ẹnikẹni li ẽwọ̀ tabi alaimọ́.
Iṣe Apo 10:28BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilẹ̀ mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́.
Iṣe Apo 10:28YCE(Yoruba Bible)
Ó sọ fún wọn pé, “Ó ye yín pé ó lòdì sí òfin wa pé kí ẹni tíí ṣe Juu kí ó ní nǹkan í ṣe pẹlu ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, tabi kí ó lọ bẹ̀ ẹ́ wò ninu ilé rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mí pé n kò gbọdọ̀ pe ẹnikẹ́ni ni eniyan lásán tabi aláìmọ́.