Fò sí àkóónú

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Iṣe Apo 10:22YBCV(Bibeli Mimọ)

Nwọn si wipe, Korneliu balogun ọrún, ọkunrin olõtọ, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si ni orukọ rere lọdọ gbogbo orilẹ-ede awọn Ju, on li a ti ọdọ Ọlọrun kọ́ nipasẹ angẹli mimọ́, lati ranṣẹ pè ọ wá si ile rẹ̀ ati lati gbọ́ ọ̀rọ li, ẹnu rẹ.

Iṣe Apo 10:22BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Wọ́n sì wí pé, “Korneliu balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtítọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ angẹli mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”

Iṣe Apo 10:22YCE(Yoruba Bible)

Wọ́n bá dáhùn pé, “Kọniliu ọ̀gágun ni ó rán wa wá; eniyan rere ni, ó sì bẹ̀rù Ọlọrun tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọmọ Juu fi lè jẹ́rìí sí i. Angẹli Oluwa ni ó sọ fún un pé kí ó ranṣẹ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀, kí ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”