Iṣe Apo 1:7-8
Iṣe Apo 1:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Kì iṣe ti nyin lati mọ̀ akoko tabi ìgba, ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararẹ̀. Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye.
Iṣe Apo 1:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe tiyín láti mọ àkókò tabi ìgbà tí Baba ti fi sí ìkáwọ́ ara rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Ṣugbọn ẹ̀yin yóo gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yin. Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo Judia ati ní Samaria ati títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”
Iṣe Apo 1:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín: ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”