Iṣe Apo 1:12-14
Iṣe Apo 1:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni nwọn pada ti ori òke ti a npè ni Olifi lọ si Jerusalemu, ti o sunmọ Jerusalemu ni ìwọn ìrin ọjọ isimi kan. Nigbati nwọn si wọle, nwọn lọ si yara oke, nibiti Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati Anderu, ati Filippi, ati Tomasi, Bartolomeu, ati Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni Selote, ati Juda arakunrin Jakọbu, gbe wà. Gbogbo awọn wọnyi fi ọkàn kan duro si adura ati si ẹ̀bẹ, pẹlu awọn obinrin, ati Maria iya Jesu ati awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu.
Iṣe Apo 1:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n pada sí Jerusalẹmu láti orí òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Òkè náà súnmọ́ Jerusalẹmu, kò tó ibùsọ̀ kan sí ìlú. Nígbà tí wọ́n wọ inú ilé, wọ́n lọ sí iyàrá òkè níbi tí wọn ń gbé. Àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ni Peteru, Johanu, Jakọbu, Anderu, Filipi, Tomasi, Batolomiu, Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni ti ẹgbẹ́ Seloti ati Judasi ọmọ Jakọbu. Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu.
Iṣe Apo 1:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerusalẹmu láti orí òkè ti a ń pè ni olifi, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan. Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí iyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni: Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu; Filipi àti Tomasi; Bartolomeu àti Matiu; Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni Sealoti, àti Judasi arákùnrin Jakọbu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Maria ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.