Iṣe Apo 1:1-14
Iṣe Apo 1:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
TEOFILU, ìhìn iṣaju ni mo ti rò, niti ohun gbogbo ti Jesu bẹ̀rẹ si iṣe, ati si ikọ́, Titi o fi di ọjọ ti a gbà a lọ soke, lẹhin ti o ti ti ipa Ẹmi Mimọ́ paṣẹ fun awọn aposteli ti o yàn: Awọn ẹniti o si farahàn fun lãye lẹhin ìjiya rẹ̀ nipa ẹ̀rí pupọ ti o daju, ẹniti a ri lọdọ wọn li ogoji ọjọ ti o nsọ ohun ti iṣe ti ijọba Ọlọrun: Nigbati o si ba wọn pejọ, o paṣẹ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe kuro ni Jerusalemu, ṣugbọn ki nwọn ki o duro dè ileri Baba, eyiti, o wipe, ẹnyin ti gbọ́ li ẹnu mi: Nitori nitotọ ni Johanu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin, kì iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ. Nitorina nigbati nwọn si pejọ, nwọn bi i lere pe, Oluwa, lati igbayi lọ iwọ ó ha mu ijọba pada fun Israeli bi? O si wi fun wọn pe, Kì iṣe ti nyin lati mọ̀ akoko tabi ìgba, ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararẹ̀. Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye. Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn. Bi nwọn si ti tẹ̀jumọ́ oju ọrun bi o ti nrè oke, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ àla duro leti ọdọ wọn; Ti nwọn si wipe, Ẹnyin ará Galili, ẽṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹ̃ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun. Nigbana ni nwọn pada ti ori òke ti a npè ni Olifi lọ si Jerusalemu, ti o sunmọ Jerusalemu ni ìwọn ìrin ọjọ isimi kan. Nigbati nwọn si wọle, nwọn lọ si yara oke, nibiti Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati Anderu, ati Filippi, ati Tomasi, Bartolomeu, ati Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni Selote, ati Juda arakunrin Jakọbu, gbe wà. Gbogbo awọn wọnyi fi ọkàn kan duro si adura ati si ẹ̀bẹ, pẹlu awọn obinrin, ati Maria iya Jesu ati awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu.
Iṣe Apo 1:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Tiofilu mi ọ̀wọ́n: Ninu ìwé mi àkọ́kọ́, mo ti sọ nípa gbogbo ohun tí Jesu ṣe ati ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ àwọn eniyan, títí di ọjọ́ tí a gbé e lọ sókè ọ̀run lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ ohun tí ó fẹ́, nípa Ẹ̀mí Mímọ́, fún àwọn aposteli tí ó ti yàn. Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun. Nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ wọn, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má kúrò ní Jerusalẹmu. Ó ní, “Ẹ dúró títí ìlérí tí Baba mí ṣe yóo fi ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ tí mo sọ fun yín. Nítorí omi ni Johanu fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín láìpẹ́ jọjọ.” Ní ọjọ́ kan tí gbogbo wọn péjọ, wọ́n bi í pé, “Oluwa, ṣé àkókò tó nisinsinyii tí ìwọ yóo gba ìjọba pada fún Israẹli?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe tiyín láti mọ àkókò tabi ìgbà tí Baba ti fi sí ìkáwọ́ ara rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Ṣugbọn ẹ̀yin yóo gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yin. Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo Judia ati ní Samaria ati títí dé òpin ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, bí wọ́n ti ń wò ó, a gbé e sókè, ìkùukùu bò ó, wọn kò sì rí i mọ́. Bí wọ́n ti tẹjú mọ́ òkè bí ó ti ń lọ, àwọn ọkunrin meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun dúró tì wọ́n. Wọ́n ní, “Ẹ̀yin ará Galili, kí ló dé tí ẹ fi dúró tí ẹ̀ ń wòkè bẹ́ẹ̀? Jesu kan náà, tí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, lọ sí ọ̀run yìí, yóo tún pada wá bí ẹ ṣe rí i tí ó ń lọ sí ọ̀run.” Wọ́n pada sí Jerusalẹmu láti orí òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Òkè náà súnmọ́ Jerusalẹmu, kò tó ibùsọ̀ kan sí ìlú. Nígbà tí wọ́n wọ inú ilé, wọ́n lọ sí iyàrá òkè níbi tí wọn ń gbé. Àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ni Peteru, Johanu, Jakọbu, Anderu, Filipi, Tomasi, Batolomiu, Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni ti ẹgbẹ́ Seloti ati Judasi ọmọ Jakọbu. Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu.
Iṣe Apo 1:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú ìwé mi ìṣáájú, Teofilu, ni mo ti kọ ní ti ohun gbogbo tí Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti kọ́ títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ pàṣẹ fún àwọn aposteli tí ó yàn Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láààyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Ní àkókò kan bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerusalẹmu, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ìlérí tí Baba mi ṣe ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi. Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.” Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọpọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Israẹli bí?” Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín: ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn; ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn. Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀yin ara Galili, èéṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run? Jesu yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run.” Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerusalẹmu láti orí òkè ti a ń pè ni olifi, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan. Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí iyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni: Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu; Filipi àti Tomasi; Bartolomeu àti Matiu; Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni Sealoti, àti Judasi arákùnrin Jakọbu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Maria ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.