II. Tim 4:5-8
II. Tim 4:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn mã ṣe pẹlẹ ninu ohun gbogbo, mã farada ipọnju, ṣe iṣẹ efangelisti, ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe. Nitori a nfi mi rubọ nisisiyi, atilọ mi si sunmọ etile. Emi ti jà ìja rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ́ mọ́: Lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidajọ ododo, yio fifun mi li ọjọ na, kì si iṣe kìki emi nikan, ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn ti o ti fẹ ifarahàn rẹ̀.
II. Tim 4:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, fi ara balẹ̀ ninu ohun gbogbo. Farada ìṣòro. Ṣe iṣẹ́ ìyìn rere. Má fi ohunkohun sílẹ̀ láì ṣe ninu iṣẹ́ iranṣẹ rẹ. Ní tèmi, a ti fi mí rúbọ ná. Àkókò ati fi ayé sílẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tó. Mo ti ja ìjà rere. Mo ti dé òpin iré ìje náà. Nisinsinyii adé òdodo náà wà nílẹ̀ fún mi, tí Oluwa onídàájọ́ òdodo yóo fún mi ní ọjọ́ náà. Èmi nìkan kọ́ ni yóo sì fún, yóo fún gbogbo àwọn tí wọn ń fi tìfẹ́tìfẹ́ retí ìfarahàn rẹ̀.
II. Tim 4:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé. Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé. Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́; Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.