II. Tim 2:14-18
II. Tim 2:14-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nkan wọnyi ni ki o mã rán wọn leti, mã kìlọ fun wọn niwaju Oluwa pe, ki nwọn ki o máṣe jijà ọ̀rọ ti kò lere, fun iparun awọn ti ngbọ. Ṣãpọn lati fi ara rẹ hàn niwaju Ọlọrun li ẹniti o yege, aṣiṣẹ́ ti kò ni lati tiju, ti o npín ọ̀rọ otitọ bi o ti yẹ. Ṣugbọn yà kuro ninu ọ̀rọ asan, nitoriti nwọn ó mã lọ siwaju ninu aiwa-bi-Ọlọrun, Ọrọ wọn yio si mã jẹ bi egbò kikẹ̀; ninu awọn ẹniti Himeneu ati Filetu wà; Awọn ẹniti o ti ṣìna niti otitọ, ti nwipe ajinde ti kọja na; ti nwọn si mbì igbagbọ́ awọn miran ṣubu.
II. Tim 2:14-18 Yoruba Bible (YCE)
Máa rán àwọn eniyan létí nípa nǹkan wọnyi. Kìlọ̀ fún wọn níwájú Ọlọrun pé kí wọn má máa jiyàn lórí oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tíí sìí máa da àwọn tí ó bá gbọ́ lọ́kàn rú. Sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe ara rẹ ní ẹni tí ó yege níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí kò ṣe ohun ìtìjú pamọ́, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ. Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán ati ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ràn irú ọ̀rọ̀ wọnyi túbọ̀ ń jìnnà sí ẹ̀sìn Ọlọrun ni. Ọ̀rọ̀ wọn dàbí egbò-rírùn tí ó ń kẹ̀ siwaju. Irú wọn ni Himeneu ati Filetu, àwọn tí wọ́n ti ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí wọn ń sọ pé ajinde tiwa ti ṣẹlẹ̀, tí wọn ń mú kí igbagbọ ẹlòmíràn yẹ̀.
II. Tim 2:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́. Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí tiwọn máa síwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀; nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Filetu wà; àwọn ẹni tí ó ti ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú.