II. Tim 2:1-4
II. Tim 2:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA, iwọ ọmọ mi, jẹ alagbara ninu ore-ọfẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu. Ati ohun wọnni ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi lati ọwọ ọ̀pọlọpọ ẹlẹri, awọn na ni ki iwọ fi le awọn olõtọ enia lọwọ, awọn ti yio le mã kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu. Ṣe alabapin pẹlu mi ninu ipọnju, bi ọmọ-ogun rere Jesu Kristi. Kò si ẹniti njàgun ti ifi ohun aiye yi dí ara rẹ̀ lọwọ, ki o le mu inu ẹniti o yàn a li ọmọ-ogun dùn.
II. Tim 2:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi, jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Kristi Jesu sọ ọ́ di alágbára. Àwọn ohun tí o gbọ́ láti ẹnu mi níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí, ni kí o fi lé àwọn olóòótọ́ eniyan lọ́wọ́, àwọn tí ó tó láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Farada ìpín tìrẹ ninu ìṣòro gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun Kristi Jesu. Kò sí ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ tún tojú bọ àwọn nǹkan ayé yòókù. Àníyàn rẹ̀ kanṣoṣo ni láti tẹ́ ọ̀gágun rẹ̀ lọ́rùn.
II. Tim 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu. Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòtítọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi. Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn.