II. Tim 2:1-2
II. Tim 2:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA, iwọ ọmọ mi, jẹ alagbara ninu ore-ọfẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu. Ati ohun wọnni ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi lati ọwọ ọ̀pọlọpọ ẹlẹri, awọn na ni ki iwọ fi le awọn olõtọ enia lọwọ, awọn ti yio le mã kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu.
Pín
Kà II. Tim 2II. Tim 2:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi, jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Kristi Jesu sọ ọ́ di alágbára. Àwọn ohun tí o gbọ́ láti ẹnu mi níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí, ni kí o fi lé àwọn olóòótọ́ eniyan lọ́wọ́, àwọn tí ó tó láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.
Pín
Kà II. Tim 2II. Tim 2:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu. Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòtítọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.
Pín
Kà II. Tim 2