II. Tim 2:1-12

II. Tim 2:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi, jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Kristi Jesu sọ ọ́ di alágbára. Àwọn ohun tí o gbọ́ láti ẹnu mi níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí, ni kí o fi lé àwọn olóòótọ́ eniyan lọ́wọ́, àwọn tí ó tó láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Farada ìpín tìrẹ ninu ìṣòro gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun Kristi Jesu. Kò sí ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ tún tojú bọ àwọn nǹkan ayé yòókù. Àníyàn rẹ̀ kanṣoṣo ni láti tẹ́ ọ̀gágun rẹ̀ lọ́rùn. Kò sí ẹni tí ó bá ń súré ìje tí ó lè gba èrè àfi bí ó bá pa òfin iré ìje mọ́. Àgbẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ lóko ni ó kọ́ ní ẹ̀tọ́ sí ìkórè oko. Gba ohun tí mò ń sọ rò. Oluwa yóo jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ yé ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ranti Jesu Kristi tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí a bí ninu ìdílé Dafidi. Ìyìn rere tí mò ń waasu nìyí. Ninu iṣẹ́ yìí ni mo ti ń jìyà títí mo fi di ẹlẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn. Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè fi ẹ̀wọ̀n de ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítorí náà, mo farada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́, kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tí ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu ògo tí ó wà títí lae. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, pé, “Bí a bá bá a kú, a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀. Bí a bá faradà á, a óo bá a jọba. Bí a bá sẹ́ ẹ, òun náà yóo sẹ́ wa.

II. Tim 2:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu. Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòtítọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi. Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn. Ní ọ̀nà kan náà, bí ẹnikẹ́ni bá sì ń díje bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso. Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo. Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi. Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà: Bi àwa bá bá a kú, àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀. Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jẹ ọba: Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa.