II. Tim 1:6-7
II. Tim 1:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori idi eyi ni mo ṣe nran ọ leti pe ki iwọ ki o mã rú ẹ̀bun Ọlọrun soke eyiti mbẹ ninu rẹ nipa gbigbe ọwọ mi le ọ. Nitoripe Ọlọrun kò fun wa ni ẹmí ibẹru; bikoṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti ọkàn ti o yè kõro.
Pín
Kà II. Tim 1II. Tim 1:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Ìdí nìyí tí mo fi ń rán ọ létí pé kí o máa rú ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ Ọlọrun sókè, tí a fi fún ọ nípa ọwọ́ mi tí mo gbé lé ọ lórí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọrun fún wa bíkòṣe ẹ̀mí agbára ati ti ìfẹ́ ati ti ìkóra-ẹni-níjàánu.
Pín
Kà II. Tim 1