II. Tim 1:5-6
II. Tim 1:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati mo ba ranti igbagbọ́ ailẹtan ti mbẹ ninu rẹ, eyiti o kọ́ wà ninu Loide iya-nla rẹ, ati ninu Eunike iya rẹ; mo si gbagbọ pe, o mbẹ ninu rẹ pẹlu. Nitori idi eyi ni mo ṣe nran ọ leti pe ki iwọ ki o mã rú ẹ̀bun Ọlọrun soke eyiti mbẹ ninu rẹ nipa gbigbe ọwọ mi le ọ.
II. Tim 1:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Mo ranti igbagbọ rẹ tí kò lẹ́tàn, tí ó kọ́kọ́ wà ninu Loisi ìyá-ìyá rẹ, ati ninu Yunisi ìyá rẹ, tí ó sì dá mi lójú pé ó wà ninu ìwọ náà. Ìdí nìyí tí mo fi ń rán ọ létí pé kí o máa rú ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ Ọlọrun sókè, tí a fi fún ọ nípa ọwọ́ mi tí mo gbé lé ọ lórí.
II. Tim 1:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá ńlá rẹ, àti nínú Eunike ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó dá mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi.